Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isikiẹli 40:12-25 BIBELI MIMỌ (BM)

12. Ògiri kan wà níwájú àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́ náà, ó ga ní igbọnwọ kan ní ẹ̀gbẹ́ kinni keji. Ati òòró ati ìbú àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́ náà jẹ́ igbọnwọ mẹfa mẹfa (mita 3).

13. Ó wọn ẹnu ọ̀nà náà láti ẹ̀yìn àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́ kan títí dé ẹ̀yìn yàrá ẹ̀gbẹ́ keji, ìbú rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ mẹẹdọgbọn (mita 12½), láti ìlẹ̀kùn kinni sí ekeji.

14. Ó tún wọn ìloro, ó jẹ́ ogún igbọnwọ (mita 9). Gbọ̀ngàn kan yí ìloro ẹnu ọ̀nà ká

15. láti iwájú ẹnu ọ̀nà ní àbáwọlé, títí kan ìloro ẹnu ọ̀nà tí ó wà ninu, jẹ́ aadọta igbọnwọ (mita 25).

16. Ẹnu ọ̀nà náà ní àwọn fèrèsé tóóró tóóró yíká, tí ó ga kan àwọn àtẹ́rígbà àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́. Bákan náà, ìloro náà ní àwọn fèrèsé yíká, àwòrán ọ̀pẹ sì wà lára àtẹ́rígbà rẹ̀.

17. Lẹ́yìn náà, ó mú mi wá sí ibi gbọ̀ngàn ti òde, mo rí àwọn yàrá ati pèpéle yíká àgbàlá náà. Ọgbọ̀n yàrá ni ó wà lára àgbàlá náà.

18. Pèpéle kan wà níbi ẹnu ọ̀nà, tí gígùn rẹ̀ rí bákan náà pẹlu ẹnu ọ̀nà, èyí ni pèpéle tí ó wà ní ìsàlẹ̀.

19. Ó wọn ibẹ̀ láti inú ẹnu ọ̀nà kúkúrú títí dé iwájú ìta gbọ̀ngàn inú, ó jẹ́ ọgọrun-un (100) igbọnwọ, (mita 45), ní ìhà ìlà oòrùn ati ìhà àríwá.

20. Lẹ́yìn náà, ó ṣiwaju mi lọ sí ìhà àríwá; ó wọn ìbú ati òòró ẹnu ọ̀nà kan tí ó wà níbẹ̀ tí ó kọjú sí ìhà àríwá, tí ó sì ṣí sí àgbàlá òde.

21. Àwọn yàrá mẹta mẹta wà ní ẹ̀gbẹ́ kinni keji. Àtẹ́rígbà ati ìloro rẹ̀ rí bákan náà pẹlu àwọn ti ẹnu ọ̀nà àkọ́kọ́. Òòró rẹ̀ jẹ́ aadọta igbọnwọ, (mita 25), ìbú rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ mẹẹdọgbọn (mita 12½).

22. Àwọn fèrèsé rẹ̀, ati ìloro rẹ̀ ati àwọn àwòrán ọ̀pẹ ara rẹ̀ rí bíi àwọn ti ẹnu ọ̀nà tí ó kọjú sí ìlà oòrùn. Ó ní àtẹ̀gùn meje, ìloro rẹ̀ sì wà ninu.

23. Níwájú ẹnu ọ̀nà ìhà àríwá, ni ẹnu ọ̀nà gbọ̀ngàn inú wà bí ó ti wà níwájú ẹnu ọ̀nà ti ìlà oòrùn. Ọkunrin náà wọn ibẹ̀ láti ẹnu ọ̀nà kan sí ikeji, ó jẹ́ ọgọrun-un (100) igbọnwọ (mita 45).

24. Ó mú mi lọ sí apá ìhà gúsù, mo sì rí ẹnu ọ̀nà kan níbẹ̀. Ó wọn àtẹ́rígbà ati ìloro rẹ̀, wọ́n sì rí bákan náà pẹlu àwọn yòókù.

25. Fèrèsé yí inú ati ìloro rẹ̀ ká, bíi àwọn fèrèsé ti àwọn ẹnu ọ̀nà yòókù. Òòró rẹ̀ jẹ́ aadọta igbọnwọ (mita 25), ìbú rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ mẹẹdọgbọn (mita 12½).

Ka pipe ipin Isikiẹli 40