Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isikiẹli 37:1-6 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Agbára OLUWA sọ̀kalẹ̀ sára mi, ẹ̀mí rẹ̀ sì gbé mi wá sinu àfonífojì tí ó kún fún egungun.

2. Ó mú mi la ààrin wọn kọjá; àwọn egungun náà pọ̀ gan-an ninu àfonífojì náà; wọ́n sì ti gbẹ.

3. OLUWA bá bi mí léèrè, ó ní, “Ìwọ ọmọ eniyan, ǹjẹ́ àwọn egungun wọnyi lè tún jí?”Mo bá dáhùn, mo ní, “OLUWA, ìwọ nìkan ni o mọ̀.”

4. Ó bá sọ fún mi pé, “Sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún àwọn egungun wọnyi, kí o wí fún wọn pé, ‘Ẹ̀yin egungun gbígbẹ wọnyi, ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA wí’.

5. Ó ní: ‘N óo mú kí èémí wọ inú yín, ẹ óo sì di alààyè.

6. N óo fi iṣan bò yín lára; lẹ́yìn náà n óo fi ara ẹran bò yín, n óo sì da awọ bò yín lára. N óo wá fi èémí si yín ninu, ẹ óo di alààyè, ẹ óo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA.’ ”

Ka pipe ipin Isikiẹli 37