Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isikiẹli 35:3-15 BIBELI MIMỌ (BM)

3. Wí fún un pé OLUWA Ọlọrun ní,‘Wò ó! Mo lòdì sí ọ,ìwọ Òkè Seiri.N óo nawọ́ ibinu sí ọ,n óo sọ ọ́ di ahoro ati aṣálẹ̀.

4. N óo sọ àwọn ìlú rẹ di aṣálẹ̀ìwọ pàápàá yóo sì di ahoro;o óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA.

5. “ ‘Nítorí pé ò ń fẹ́ràn ati máa ṣe ọ̀tá lọ títí, o sì fa àwọn ọmọ Israẹli fún ogun pa nígbà tí ìṣòro dé bá wọn, tí wọn ń jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn.

6. Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun ní, mo fi ara mi búra pé, n óo fi ọ́ fún ikú pa, ikú yóo máa lépa rẹ, nítorí pé apànìyàn ni ọ́; ikú yóo máa lépa ìwọ náà.

7. N óo sọ òkè Seiri di aṣálẹ̀ ati ahoro. N óo pa gbogbo àwọn tí ń lọ tí ń bọ̀ níbẹ̀.

8. N óo da òkú sí orí àwọn òkè ńláńlá rẹ, yóo kún. Bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn òkè kéékèèké rẹ, ati gbogbo àwọn àfonífojì rẹ, ati gbogbo ipa odò rẹ. Òkú àwọn tí a fi idà pa ni yóo kúnbẹ̀.

9. N óo sọ ọ́ di ahoro títí lae, ẹnikẹ́ni kò sì ní gbé inú àwọn ìlú rẹ mọ́. O óo wá mọ̀ nígbà náà pé èmi ni OLUWA.

10. “ ‘Nítorí ẹ̀yin ará Edomu sọ pé, àwọn orílẹ̀-èdè mejeeji wọnyi ati ilẹ̀ wọn yóo di tiyín ati pé ẹ óo jogún rẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé OLUWA wà níbẹ̀.

11. Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun ní, mo fi ara mi búra, bí ẹ ti fi ìrúnú ati owú ṣe sí wọn nítorí pé ẹ kórìíra wọn, bẹ́ẹ̀ gan-an ni èmi náà óo ṣe sí ọ; n óo sì jẹ́ kí ẹ mọ irú ẹni tí mo jẹ́ nígbà tí mo bá dájọ́ fun yín.

12. Ẹ óo mọ̀ pé èmi OLUWA gbọ́ gbogbo ohun tí ẹ̀ ń sọ sí àwọn òkè Israẹli, pé wọ́n ti di ahoro ati ìkógun fun yín.

13. Ẹ̀ ń fi ẹnu yín sọ̀rọ̀ ìgbéraga sí mi, ẹ sì ń dá àpárá lù mí; gbogbo rẹ̀ ni mo gbọ́.’ ”

14. OLUWA Ọlọrun ní, “N óo sọ ìwọ Edomu di ahoro, kí gbogbo ayé lè yọ̀ ọ́;

15. bí o ti yọ ilẹ̀ Israẹli nígbà tí ilé wọn di ahoro. Bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe sí ọ, ìwọ náà óo di ahoro. Gbogbo òkè Seiri ati gbogbo ilẹ̀ Edomu yóo di ahoro. Ẹ óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA.”

Ka pipe ipin Isikiẹli 35