Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isikiẹli 29:1-7 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ní ọjọ́ kejila oṣù kẹwaa ọdún kẹwaa, OLUWA bá mi sọ̀rọ̀;

2. Ó ní, “Ìwọ ọmọ eniyan, kọjú rẹ sí Farao ọba Ijipti, kí o sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa òun ati gbogbo àwọn ará Ijipti pé,

3. OLUWA Ọlọrun ní: Wò ó, mo lòdì sí ọ, ìwọ Farao, ọba Ijipti, Ìwọ diragoni ńlá tí o wà láàrin odò rẹ; tí o wí pé, ‘Èmi ni mo ni odò Naili mi; ara mi ni mo dá a fún.’

4. N óo fi ìwọ̀ kọ́ ọ lẹ́nu, n óo sì jẹ́ kí àwọn ẹja inú odò Naili so mọ́ ìpẹ́ rẹ; n óo sì fà ọ́ jáde kúrò ninu odò Naili rẹ pẹlu gbogbo àwọn ẹja inú odò rẹ tí wọn óo so mọ́ ọ lára.

5. N óo gbé ọ jù sinu aṣálẹ̀, ìwọ ati gbogbo ẹja inú odò Naili rẹ. Ẹ ó bọ́ lulẹ̀ ninu pápá tí ó tẹ́jú. Ẹnìkan kò sì ní kó òkú yín jọ, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní sin yín. Mo ti fi yín ṣe oúnjẹ fún àwọn ẹranko ati àwọn ẹyẹ.

6. Gbogbo àwọn tí wọn ń gbé Ijipti yóo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA. “Nítorí pé ẹ fi ara yín ṣe ọ̀pá tí àwọn ọmọ Israẹli gbára lé; ṣugbọn ọ̀pá tí kò gbani dúró ni yín.

7. Nígbà tí wọ́n gba yín mú, dídá ni ẹ dá mọ́ wọn lọ́wọ́, tí ẹ ya wọ́n léjìká pẹ́rẹpẹ̀rẹ. Nígbà tí wọ́n gbára le yín, ẹ dá ẹ sì jẹ́ kí wọ́n dá lẹ́yìn.”

Ka pipe ipin Isikiẹli 29