1. Ní ọjọ́ kejila oṣù kẹwaa ọdún kẹwaa, OLUWA bá mi sọ̀rọ̀;
2. Ó ní, “Ìwọ ọmọ eniyan, kọjú rẹ sí Farao ọba Ijipti, kí o sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa òun ati gbogbo àwọn ará Ijipti pé,
3. OLUWA Ọlọrun ní: Wò ó, mo lòdì sí ọ, ìwọ Farao, ọba Ijipti, Ìwọ diragoni ńlá tí o wà láàrin odò rẹ; tí o wí pé, ‘Èmi ni mo ni odò Naili mi; ara mi ni mo dá a fún.’
4. N óo fi ìwọ̀ kọ́ ọ lẹ́nu, n óo sì jẹ́ kí àwọn ẹja inú odò Naili so mọ́ ìpẹ́ rẹ; n óo sì fà ọ́ jáde kúrò ninu odò Naili rẹ pẹlu gbogbo àwọn ẹja inú odò rẹ tí wọn óo so mọ́ ọ lára.
5. N óo gbé ọ jù sinu aṣálẹ̀, ìwọ ati gbogbo ẹja inú odò Naili rẹ. Ẹ ó bọ́ lulẹ̀ ninu pápá tí ó tẹ́jú. Ẹnìkan kò sì ní kó òkú yín jọ, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní sin yín. Mo ti fi yín ṣe oúnjẹ fún àwọn ẹranko ati àwọn ẹyẹ.