Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isikiẹli 23:25-31 BIBELI MIMỌ (BM)

25. N óo dojú kọ ọ́ pẹlu ibinu, n óo jẹ́ kí wọ́n fi ìrúnú bá ọ jà. Wọn óo gé ọ ní etí ati imú, wọn óo sì fi idà pa àwọn eniyan rẹ tí wọ́n kù. Wọn óo kó àwọn ọmọ rẹ ọkunrin ati obinrin lọ, wọn óo sì dáná sun àwọn tí wọ́n kù.

26. Wọn yóo bọ́ aṣọ lára rẹ; wọn yóo kó gbogbo nǹkan ọ̀ṣọ́ rẹ lọ.

27. Bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe fi òpin sí ìṣekúṣe ati àgbèrè tí o kó ti ilẹ̀ Ijipti wá. O kò ní ṣíjú wo àwọn ará Ijipti mọ́, o kò sì ní ranti wọn mọ́.”

28. OLUWA ní, “Mo ṣetán tí n óo fi ọ́ lé àwọn tí o kórìíra lọ́wọ́, àwọn tí ọkàn rẹ yipada kúrò lọ́dọ̀ wọn pẹlu ìríra.

29. Ìkórìíra ni wọn yóo fi máa bá ọ gbé, wọn yóo kó gbogbo èrè iṣẹ́ ọwọ́ rẹ lọ, wọn yóo sì fi ọ́ sílẹ̀ ní ìhòòhò goloto. Wọn yóo tú ọ sí ìhòòhò, gbogbo ayé yóo sì mọ̀ pé aṣẹ́wó ni ọ́. Ìṣekúṣe ati àgbèrè rẹ ni

30. ó mú èyí wá sórí rẹ, nítorí o ti bá àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn ṣe àgbèrè, o sì ti fi oriṣa wọn ba ara rẹ jẹ́.

31. Ìwà tí ẹ̀gbọ́n rẹ hù ni ìwọ náà ń hù, nítorí náà, ìyà tí mo fi jẹ ẹ̀gbọ́n rẹ ni n óo fi jẹ ìwọ náà.”

Ka pipe ipin Isikiẹli 23