Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isikiẹli 18:1-12 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA tún bá mi sọ̀rọ̀, ó bi mí pé:

2. “Kí ni ẹ rí tí ẹ fi ń pa irú òwe yìí nípa ilẹ̀ Israẹli, tí ẹ̀ ń sọ pé,‘Àwọn baba ni wọ́n jẹ èso àjàrà tí ó kan,ni eyín fi kan àwọn ọmọ?’

3. “Mo fi ara mi búra pé, ẹ kò ní pa òwe yìí mọ́ ní ilẹ̀ Israẹli.

4. Èmi ni mo ni ẹ̀mí gbogbo eniyan, tèmi ni ẹ̀mí baba ati ẹ̀mí ọmọ; ẹni yòówù tó bá dẹ́ṣẹ̀ ni yóo kú.

5. “Bí ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ olódodo, tí ó ń ṣe ohun tí ó tọ́, tí ó sì bá òfin mu;

6. bí kò bá bá wọn jẹ ẹbọ lórí àwọn òkè, tabi kí ó bọ àwọn oriṣa ilé Israẹli; tí kò bá bá aya aládùúgbò rẹ̀ lòpọ̀, tabi kí ó bá obinrin lòpọ̀ ní àkókò tí ó ń ṣe nǹkan oṣù rẹ̀ lọ́wọ́;

7. tí kò ni ẹnikẹ́ni lára, ṣugbọn tí ó dá ohun tí onígbèsè fi ṣe ìdúró pada fún un; tí kò fi ipá jalè, tí ó ń fún ẹni tí ebi ń pa ní oúnjẹ, tí ó sì ń da aṣọ bo ẹni tí ó wà ní ìhòòhò,

8. tí kò gba owó èlé lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni, tí ó yàgò fún ẹ̀ṣẹ̀, tí ó ń dá ẹjọ́ ẹ̀tọ́ láàrin ẹni meji,

9. tí ó ń rìn ninu ìlànà mi, tí ó sì ń fi tọkàntọkàn pa òfin mi mọ́, olódodo ni irú ẹni bẹ́ẹ̀, yóo sì yè. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

10. “Bí irú ẹni bẹ́ẹ̀ bá bí ọmọ, tí ọmọ yìí ń fi ipá jalè, tí ń pa eniyan, tí kò ṣe ọ̀kankan ninu gbogbo ohun tí a kà sílẹ̀ pé baba ń ṣe,

11. ṣugbọn tí ó ń jẹ ẹbọ lórí àwọn òkè, tí ó ń bá aya aládùúgbò rẹ̀ lòpọ̀;

12. tí ń ni talaka ati aláìní lára, tí ń fi ipá jalè, tí kì í dá ohun tí onígbèsè rẹ̀ bá fi ṣe ìdúró pada fún un, tí ń bọ oriṣa, tí ń ṣe ohun ìríra,

Ka pipe ipin Isikiẹli 18