Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isikiẹli 15:1-6 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní:

2. “Ìwọ ọmọ eniyan, ọ̀nà wo ni ẹ̀ka igi àjàrà gbà dára ju ẹ̀ka igi yòókù lọ; àní igi àjàrà tí ó wà láàrin àwọn igi inú igbó?

3. Ǹjẹ́ ẹnìkan a máa fi igi rẹ̀ ṣe ohunkohun? Àbí wọn a máa gé lára rẹ̀ kí wọn fi gbẹ́ èèkàn tí wọ́n fi ń so nǹkan mọ́lẹ̀?

4. Iná ni wọ́n ń fi í dá, nígbà tí iná bá jó o lórí, tí ó jó o nídìí, tí ó sì sọ ààrin rẹ̀ di èédú, ṣé ó tún ṣe é fi ṣe ohunkohun?

5. Nígbà tí ó wà ní odidi, kò wúlò fún nǹkankan. Nígbà tí iná ti jó o, tí ó ti di èédú, ṣé eniyan tún lè fi ṣe ohunkohun?”

6. Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun ní, “Bí ẹ̀ka àjàrà tí mo sọ di igi ìdáná láàrin àwọn igi, bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe àwọn tí ń gbé Jerusalẹmu.

Ka pipe ipin Isikiẹli 15