orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28
  29. 29
  30. 30
  31. 31
  32. 32
  33. 33
  34. 34
  35. 35
  36. 36
  37. 37
  38. 38
  39. 39
  40. 40
  41. 41
  42. 42
  43. 43
  44. 44
  45. 45
  46. 46
  47. 47
  48. 48

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isikiẹli 15 BIBELI MIMỌ (BM)

Òwe Nípa Igi Àjàrà

1. OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní:

2. “Ìwọ ọmọ eniyan, ọ̀nà wo ni ẹ̀ka igi àjàrà gbà dára ju ẹ̀ka igi yòókù lọ; àní igi àjàrà tí ó wà láàrin àwọn igi inú igbó?

3. Ǹjẹ́ ẹnìkan a máa fi igi rẹ̀ ṣe ohunkohun? Àbí wọn a máa gé lára rẹ̀ kí wọn fi gbẹ́ èèkàn tí wọ́n fi ń so nǹkan mọ́lẹ̀?

4. Iná ni wọ́n ń fi í dá, nígbà tí iná bá jó o lórí, tí ó jó o nídìí, tí ó sì sọ ààrin rẹ̀ di èédú, ṣé ó tún ṣe é fi ṣe ohunkohun?

5. Nígbà tí ó wà ní odidi, kò wúlò fún nǹkankan. Nígbà tí iná ti jó o, tí ó ti di èédú, ṣé eniyan tún lè fi ṣe ohunkohun?”

6. Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun ní, “Bí ẹ̀ka àjàrà tí mo sọ di igi ìdáná láàrin àwọn igi, bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe àwọn tí ń gbé Jerusalẹmu.

7. N óo dójú lé wọn, bí wọn tilẹ̀ yọ jáde ninu iná, sibẹsibẹ iná ni yóo jó wọn. Nígbà tí mo bá dójú lé wọn, ẹ óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA.

8. N óo sọ ilẹ̀ náà di ahoro nítorí pé wọ́n ti hùwà aiṣootọ. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”