Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isikiẹli 14:15-23 BIBELI MIMỌ (BM)

15. “Bí mo bá jẹ́ kí àwọn ẹranko burúkú já wọ orílẹ̀-èdè náà, kí wọ́n pa wọ́n lọ́mọ jẹ, tí wọ́n sọ ilẹ̀ náà di ahoro, tí ẹnikẹ́ni kò lè gba ibẹ̀ kọjá mọ́, nítorí àwọn ẹranko tí wọ́n wà níbẹ̀,

16. bí Noa, ati Daniẹli ati Jobu bá tilẹ̀ wà níbẹ̀, bí èmi OLUWA Ọlọrun fi ara mi búra pé, wọn kò ní lè gba ọmọkunrin tabi ọmọbinrin wọn là. Ara wọn nìkan ni wọn yóo lè gbàlà, ilẹ̀ náà yóo sì di ahoro.

17. Bí mo bá mú kí ogun jà ní ilẹ̀ náà, tí mo sì pa eniyan ati ẹranko run ninu rẹ̀,

18. bí àwọn ọkunrin mẹta náà bá tilẹ̀ wà níbẹ̀, bí èmi OLUWA ti wà láàyè, wọn kò ní lè gba ọmọkunrin tabi ọmọbinrin wọn là. Ara wọn nìkan ni wọn yóo lè gbàlà.

19. “Tabi bí mo bá rán àjàkálẹ̀ àrùn sí orílẹ̀-èdè náà, tí mo sì fi ibinu bá a jà, débi pé eniyan kú níbẹ̀, tí mo pa ati eniyan ati ẹranko run ninu rẹ̀,

20. bí Noa, Daniẹli ati Jobu bá tilẹ̀ wà níbẹ̀, èmi OLUWA Ọlọrun fi ara mi búra pé, wọn kò ní lè gba ọmọkunrin tabi ọmọbinrin wọn là. Ara wọn nìkan ni wọn yóo lè fi òdodo wọn gbàlà.”

21. Nítorí OLUWA Ọlọrun ní, “Báwo ni yóo ti wá burú tó nisinsinyii tí mo rán ìjẹníyà burúkú mẹrin wọnyi sí Jerusalẹmu: ogun, ìyàn, ẹranko burúkú ati àjàkálẹ̀ àrùn láti pa eniyan ati ẹranko run ninu rẹ̀.

22. Sibẹ bí a bá rí àwọn tí wọ́n yè ninu wọn lọkunrin ati lobinrin, tí wọ́n bá wá sọ́dọ̀ rẹ, tí o rí ìwà ati ìṣe wọn, o óo gbà pé mo jàre ní ti ibi tí mo jẹ́ kí ó ṣẹlẹ̀ sí Jerusalẹmu.

23. Wọn yóo jẹ́ ìtùnú fún ọ nígbà tí o bá rí ìwà ati ìṣe wọn, O óo sì mọ̀ pé bí kò bá nídìí, n kò ní ṣe gbogbo ohun tí mo ṣe sí wọn. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

Ka pipe ipin Isikiẹli 14