Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Hosia 2:11-21 BIBELI MIMỌ (BM)

11. N óo fi òpin sí ayọ̀ rẹ̀ ati ọjọ́ àsè rẹ̀, ọjọ́ oṣù tuntun rẹ̀, ọjọ́ ìsinmi rẹ̀, ati gbogbo àjọ̀dún tí ó ti yà sọ́tọ̀.

12. N óo run gbogbo igi àjàrà ati igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀, àwọn ohun tí ó ń pè ní owó ọ̀yà, tí àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ san fún un. N óo sọ ọgbà rẹ̀ di igbó, àwọn ẹranko ìgbẹ́ yóo sì jẹ wọ́n ní àjẹrun.

13. N óo jẹ ẹ́ níyà fún àwọn ọjọ́ tí ó yà sọ́tọ̀, tí ó fi ń sun turari sí àwọn oriṣa Baali, tí ó kó àwọn ohun ọ̀ṣọ́ rẹ̀ sára, tí ó ń sá tẹ̀lé àwọn olólùfẹ́ rẹ̀, tí ó sì gbàgbé mi. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

14. Nítorí náà, n óo tàn án lọ sinu aṣálẹ̀, n óo bá a sọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́.

15. N óo sì fún un ní àwọn ọgbà àjàrà rẹ̀ pada níbẹ̀, n óo sì sọ àfonífojì Akori di Ẹnu Ọ̀nà Ìrètí. Yóo kọrin fún mi bí ó tí ń ṣe ní ìgbà èwe rẹ̀, nígbà tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ti ilẹ̀ Ijipti dé.

16. OLUWA ní, nígbà tí ó bá yá, yóo máa pè mí ní ọkọ rẹ̀, kò ní pè mí ní Baali rẹ̀ mọ́.

17. Nítorí pé, n óo gba orúkọ Baali kúrò lẹ́nu rẹ̀, kò sì ní dárúkọ rẹ̀ mọ́.

18. Nígbà náà ni n óo tìtorí tirẹ̀ bá àwọn ẹranko, àwọn ẹyẹ, ati àwọn nǹkan tí ń fi àyà fà lórí ilẹ̀ dá majẹmu, n óo sì mú ọfà, idà, ati ogun kúrò ní ilẹ̀ náà. N óo jẹ́ kí ẹ máa gbé ní alaafia ati ní àìléwu.

19. Ìwọ Israẹli, n óo sọ ọ́ di iyawo mi títí lae;n óo sọ ọ́ di iyawo mi lódodo ati lótìítọ́,ninu ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ ati àánú.

20. N óo sọ ọ́ di iyawo mi, lótìítọ́, o óo sì mọ̀ mí ní OLUWA.

21. OLUWA ní,“Ní ọjọ́ náà, n óo dáhùn adura ojú ọ̀run,ojú ọ̀run yó sì dáhùn adura ilẹ̀.

Ka pipe ipin Hosia 2