Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Habakuku 3:11-19 BIBELI MIMỌ (BM)

11. Oòrùn ati òṣùpá dúró ní ipò wọn,nígbà tí ọfà rẹ ń já lọ ṣòòrò,tí àwọn ọ̀kọ̀ rẹ náà ń kọ mànà,bí wọ́n ti ń fò lọ.

12. O la ayé kọjá pẹlu ibinu,o sì fi ibinu tẹ àwọn orílẹ̀-èdè mọ́lẹ̀.

13. O jáde lọ láti gba àwọn eniyan rẹ là,láti gba àwọn àyànfẹ́ rẹ là.O wó orí aṣiwaju ilẹ̀ àwọn ẹni ibi wómúwómú,o tú u sí ìhòòhò láti itan dé ọrùn.

14. O fi ọ̀kọ̀ rẹ gún orí àwọn olórí ogun;àwọn tí wọ́n wá bí ìjì líleláti tú wa ká,tí wọn ń yọ̀ bí ẹni tí ń ni talaka lára níkọ̀kọ̀.

15. O fi àwọn ẹṣin rẹ tẹ òkun mọ́lẹ̀;wọ́n tẹ ríru omi mọ́lẹ̀.

16. Mo gbọ́, àyà mi sì lù kìkì,ètè mi gbọ̀n pẹ̀pẹ̀nígbà tí mo gbọ́ ìró rẹ̀;egungun mi bẹ̀rẹ̀ sí rà,ẹsẹ̀ mi ń gbọ̀n rìrì nílẹ̀.N óo fi sùúrù dúró jẹ́ẹ́ de ọjọ́ tí ìṣòro yóo débá àwọn tí wọ́n kó wa lẹ́rù.

17. Bí igi ọ̀pọ̀tọ́ kò tilẹ̀ rúwé,tí àjàrà kò sì so,tí kò sí èso lórí igi olifi;tí àwọn irúgbìn kò sì so lóko,tí àwọn agbo aguntan run,tí kò sì sí mààlúù ninu agbo mọ́,

18. sibẹsibẹ, n óo yọ̀ ninu OLUWA,n óo yọ̀ ninu Ọlọrun Olùgbàlà mi.

19. Ọlọrun, OLUWA, ni agbára mi;Ó mú kí ẹsẹ̀ mi yá nílẹ̀ bíi ti àgbọ̀nrín,ó mú mi rìn lórí àwọn òkè gíga.(Sí ọ̀gá akọrin; pẹlu àwọn ohun èlò orin olókùn.)

Ka pipe ipin Habakuku 3