Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹsira 7:23-28 BIBELI MIMỌ (BM)

23. Kí ẹ rí i pé ẹ tọ́jú gbogbo nǹkan tí Ọlọrun ọ̀run bá pa láṣẹ fún lílò ninu Tẹmpili rẹ̀, kí ibinu rẹ̀ má baà wá sórí ibùjókòó ọba ati àwọn ọmọ rẹ̀.

24. A tún fi ń ye yín pé kò bá òfin mu láti gba owó ìṣákọ́lẹ̀, tabi owó bodè, tabi owó orí lọ́wọ́ àwọn alufaa, tabi àwọn ọmọ Lefi, tabi àwọn akọrin, tabi àwọn aṣọ́nà, tabi àwọn òṣìṣẹ́ tẹmpili, tabi àwọn òṣìṣẹ́ mìíràn ninu ilé Ọlọrun.

25. “Kí ìwọ Ẹsira, lo ọgbọ́n tí Ọlọrun rẹ fún ọ, kí o yan àwọn alákòóso ati àwọn adájọ́ tí wọ́n mọ òfin Ọlọrun rẹ, kí wọ́n lè máa ṣe ìdájọ́ àwọn tí wọ́n wà ní agbègbè òdìkejì odò. Kí o sì kọ́ àwọn tí kò mọ òfin Ọlọrun rẹ kí àwọn náà lè mọ̀ ọ́n.

26. Ẹnikẹ́ni tí kò bá tẹríba fún òfin Ọlọrun rẹ ati àṣẹ ọba, pípa ni a óo pa á, tabi kí á wà á lọ kúrò ní ìlú, tabi kí á gba dúkìá rẹ̀, tabi kí á gbé e sọ sẹ́wọ̀n.”

27. Ẹsira bá dáhùn pé, “Ìyìn ni fún OLUWA, Ọlọrun àwọn baba wa, tí ó fi sí ọba lọ́kàn láti ṣe ọ̀ṣọ́ sí tẹmpili Ọlọrun ní Jerusalẹmu,

28. tí ó fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ hàn mí níwájú ọba, pẹlu àwọn ìgbìmọ̀ ati àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ pataki pataki. Nítorí pé OLUWA Ọlọrun wà pẹlu mi, mo ṣe ọkàn gírí, mo kó àwọn aṣiwaju àwọn ọmọ Israẹli jọ, mo ní kí wọ́n bá mi kálọ.”

Ka pipe ipin Ẹsira 7