Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹsira 6:12-19 BIBELI MIMỌ (BM)

12. Kí Ọlọrun, tí ó yan Jerusalẹmu gẹ́gẹ́ bí ibi ìsìn rẹ̀, pa ẹni náà run, kì báà ṣe ọba tabi orílẹ̀-èdè kan ni ó bá tàpá sí òfin yìí, tí ó sì ń wá ọ̀nà láti wó ilé Ọlọrun tí ó wà ní Jerusalẹmu. Èmi Dariusi ọba ni mo pa àṣẹ yìí, ẹ sì gbọdọ̀ mú un ṣẹ fínnífínní.”

13. Tatenai, gomina, Ṣetari Bosenai ati àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn tẹ̀lé gbogbo àṣẹ tí Dariusi ọba pa fún wọn lẹ́sẹẹsẹ.

14. Àwọn àgbààgbà Juu ń kọ́ ilé náà, wọ́n sì ń ṣe àṣeyọrí pẹlu ìdálọ́kànle tí àsọtẹ́lẹ̀ tí wolii Hagai ati Sakaraya, ọmọ Ido ń fún wọn. Wọ́n parí kíkọ́ tẹmpili náà bí Ọlọrun Israẹli ti pa á láṣẹ fún wọn ati gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Kirusi, ati ti Dariusi ati ti Atasasesi, àwọn ọba Pasia.

15. Wọ́n parí kíkọ́ Tẹmpili náà ní ọjọ́ kẹta oṣù Adari, ní ọdún kẹfa ìjọba Dariusi.

16. Gbogbo àwọn ọmọ Israẹli: àwọn alufaa, àwọn ẹ̀yà Lefi ati àwọn tí wọ́n ti oko ẹrú pada dé bá fi tayọ̀tayọ̀ ṣe ayẹyẹ ìyàsímímọ́ tẹmpili náà.

17. Ọgọrun-un ọ̀dọ́ akọ mààlúù, igba (200) àgbò, ati irinwo (400) ọ̀dọ́ aguntan ni wọ́n fi rú ẹbọ ìyàsímímọ́ náà. Wọ́n sì fi ewúrẹ́ kọ̀ọ̀kan rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ fún ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu ẹ̀yà Israẹli mejeejila.

18. Wọ́n sì fi àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi sí ipò wọn ninu iṣẹ́ ìsìn inú Tẹmpili, ní Jerusalẹmu, gẹ́gẹ́ bí a ṣe kọ ọ́ sílẹ̀ ninu ìwé Mose.

19. Ní ọjọ́ kẹrinla, oṣù kinni ọdún tí ó tẹ̀lé e, àwọn Juu tí wọ́n pada láti oko ẹrú ṣe ayẹyẹ Àjọ Ìrékọjá.

Ka pipe ipin Ẹsira 6