Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹsira 5:1-10 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Wolii Hagai ati wolii Sakaraya, ọmọ Ido, bẹ̀rẹ̀ sí sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún àwọn Juu tí wọ́n wà ni Juda ati Jerusalẹmu ní orúkọ Ọlọrun Israẹli, ẹni tí ó jẹ́ orí fún wọn.

2. Nígbà tí Serubabeli, ọmọ Ṣealitieli ati Jeṣua, ọmọ Josadaki gbọ́ ọ̀rọ̀ wọn, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́ lórí àtikọ́ ilé Ọlọrun ní Jerusalẹmu, àwọn wolii Ọlọrun mejeeji sì ń ràn wọ́n lọ́wọ́.

3. Ní àkókò kan náà, Tatenai, gomina agbègbè òdìkejì odò ati Ṣetari Bosenai ati gbogbo àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn wá sí ọ̀dọ̀ wọn, wọ́n bi wọ́n léèrè pé: “Ta ló fun yín láṣẹ láti kọ́ tẹmpili yìí ati láti dá àwọn nǹkan inú rẹ̀ pada sibẹ?

4. Ati pé, kí ni orúkọ àwọn tí wọ́n ń kọ́ ilé yìí?”

5. Ṣugbọn Ọlọrun wà pẹlu àwọn olórí Juu, wọn kò sì lè dá wọn dúró títí tí wọn fi kọ̀wé sí Dariusi ọba, tí wọ́n sì rí èsì ìwé náà gbà.

6. Ohun tí Tatenai ati Ṣetari Bosenai ati àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn kọ sinu ìwé sí Dariusi ọba nìyí:

7. “Sí Dariusi ọba, kí ọba ó pẹ́.

8. “A fẹ́ kí ọba mọ̀ pé, a lọ sí agbègbè Juda, a sì dé ilé tí wọ́n kọ́ fún Ọlọrun tí ó tóbi. Òkúta ńláńlá ni wọ́n fi ń kọ́ ọ, wọ́n sì ń tẹ́ pákó sára ògiri rẹ̀. Tọkàntọkàn ni wọ́n fi ń ṣe iṣẹ́ náà, ó sì ń tẹ̀síwájú.

9. “A bèèrè lọ́wọ́ àwọn àgbààgbà wọn pé, ta ló fun wọn láṣẹ láti tún tẹmpili yìí kọ́ ati láti dá àwọn nǹkan inú rẹ̀ pada sibẹ.

10. A bèèrè orúkọ wọn, kí á baà lè kọ orúkọ olórí wọn sílẹ̀ láti fi ranṣẹ sí kabiyesi.

Ka pipe ipin Ẹsira 5