Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹsira 2:61-70 BIBELI MIMỌ (BM)

61. Àwọn tí wọ́n jẹ́ ọmọ alufaa ninu wọn nìwọ̀nyí: àwọn ọmọ Habaya, àwọn ọmọ Hakosi, ati àwọn ọmọ Basilai (tí ó fẹ́ aya ninu ìdílé Basilai ará Gileadi, tí wọ́n sì ń fi orúkọ àna rẹ̀ pe àwọn ọmọ rẹ̀).

62. Wọ́n wá orúkọ wọn ninu ìwé àkọsílẹ̀ tí a kọ ní ìdílé ìdílé, ṣugbọn wọn kò rí i. Nítorí náà a kà wọ́n kún aláìmọ́, a sì yọ wọ́n kúrò ninu iṣẹ́ alufaa.

63. Gomina sọ fún wọn pé wọn kò gbọdọ̀ jẹ ninu àwọn oúnjẹ mímọ́ jùlọ, títí tí wọn yóo fi rí alufaa kan tí ó lè lo Urimu ati Tumimu láti wádìí lọ́wọ́ OLUWA.

64. Àpapọ̀ gbogbo àwọn tí wọ́n ti oko ẹrú dé jẹ́ ọ̀kẹ́ meji ó lé ẹgbaa, ó lé ọtalelọọdunrun (42,360).

65. Láìka àwọn iranṣẹkunrin ati àwọn iranṣẹbinrin wọn tí wọ́n jẹ́ ẹẹdẹgbaarin ó lé ojilelọọdunrun ó dín mẹta (7,337). Wọ́n sì tún ní igba (200) akọrin lọkunrin, ati lobinrin.

66. Àwọn ohun ọ̀sìn tí wọ́n kó bọ̀ nìwọ̀nyí: ẹṣin wọn jẹ́ ẹẹdẹgbẹrin ó lé mẹrindinlogoji (736) akọ mààlúù wọn jẹ́ igba ó lé marundinlaadọta (245)

67. Ràkúnmí wọn jẹ́ irinwo ó lé marundinlogoji (435), kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn jẹ́ ẹgbaata ó lé okoolelẹẹdẹgbẹrin (6,720).

68. Nígbà tí wọ́n dé ilé OLUWA ní Jerusalẹmu, díẹ̀ ninu àwọn olórí ìdílé náà fi ọrẹ àtinúwá sílẹ̀ láti tún ilé Ọlọrun kọ́ sí ààyè rẹ̀.

69. Wọ́n ṣe gẹ́gẹ́ bí agbára wọn ti tó. Wọ́n fi ọọdunrun ó lé mejila (312) kilogiramu wúrà ẹgbẹsan (1,800) kilogiramu fadaka ati ọgọrun-un (100) ẹ̀wù alufaa, ṣe ẹ̀bùn fún ilé OLUWA.

70. Àwọn alufaa, àwọn ọmọ Lefi ati àwọn kan ninu àwọn eniyan náà ń gbé Jerusalẹmu ati agbègbè rẹ̀. Àwọn akọrin, àwọn aṣọ́nà ati àwọn òṣìṣẹ́ tẹmpili ń gbé àwọn ìlú tí ó wà nítòsí wọn, àwọn ọmọ Israẹli yòókù sì ń gbé àwọn ìlú wọn.

Ka pipe ipin Ẹsira 2