Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹsira 1:6-10 BIBELI MIMỌ (BM)

6. Àwọn aládùúgbò wọn fi ohun èlò fadaka ati ti wúrà, ati dúkìá, ati ẹran ọ̀sìn, ati àwọn nǹkan olówó iyebíye ràn wọ́n lọ́wọ́, yàtọ̀ sí àwọn ọrẹ àtinúwá.

7. Kirusi ọba náà kó àwọn ohun èlò inú ilé OLUWA jáde, tí Nebukadinesari kó wá sinu àwọn ilé oriṣa rẹ̀, láti Jerusalẹmu.

8. Kirusi ọba fún Mitiredati, akápò ìjọba rẹ̀ ní àṣẹ láti kó wọn síta, ó sì kà wọ́n ní ọ̀kọ̀ọ̀kan fún Ṣeṣibasari, olórí ẹ̀yà Juda.

9. Iye àwọn nǹkan náà nìyí:Ẹgbẹrun kan (1,000) àwo wúrà,ẹgbẹrun kan (1,000) àwo fadaka,àwo turari mọkandinlọgbọn;

10. ọgbọ̀n àwokòtò wúrà,ẹgbaa ó lé irinwo ati mẹ́wàá (2,410) àwo fadaka kéékèèké,ẹgbẹrun (1,000) oríṣìíríṣìí ohun èlò mìíràn.

Ka pipe ipin Ẹsira 1