Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkún Jeremaya 4:1-12 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Wo bí wúrà ti dọ̀tí,tí ojúlówó wúrà sì yipada;tí àwọn òkúta Tẹmpili mímọ́ sì fọ́nká ní gbogbo ìkóríta.

2. Ẹ wo àwọn ọdọmọkunrin Sioni,àwọn ọmọ tí wọn níye lórí bí ojúlówó wúrà,tí a wá ń ṣe bí ìkòkò amọ̀;àní, bí ìkòkò amọ̀ lásánlàsàn.

3. Àwọn ajáko a máa fún àwọn ọmọ wọn lọ́mú.Ṣugbọn àwọn eniyan mi ti di ìkà,bí ògòǹgò inú aṣálẹ̀.

4. Ahọ́n ọmọ ọmú lẹ̀ mọ́ òkè ẹnu rẹ̀ nítorí òùngbẹ.Àwọn ọmọde ń tọrọ oúnjẹ,ṣugbọn kò sí ẹni tí ó fún wọn.

5. Àwọn tí wọn tí ń jẹ oúnjẹ àdídùndi ẹni tí ń ṣa ilẹ̀ jẹ kiri ní ìgboro.Àwọn tí wọn tí ń fi aṣọ àlàárì boradi ẹni tí ń sùn lórí òkítì eérú.

6. Ìjìyà àwọn eniyan mi pọ̀ ju ti àwọn ará Sodomu lọ,Sodomu tí ó parun lójijì,láìjẹ́ pé eniyan fi ọwọ́ kàn án.

7. Àwọn olórí wọn kò ní àléébù kankan,Ọwọ́ wọn mọ́, inú wọn funfun nini,wọ́n dára ju egbin lọ,ẹwà wọn sì dàbí ẹwà iyùn.

8. Ṣugbọn nisinsinyii, ojú wọn dúdú ju èédú lọ,kò sí ẹni tí ó dá wọn mọ̀ láàrin ìgboro,awọ ara wọn ti hunjọ lórí egungun wọn,wọ́n wá gbẹ bí igi.

9. Ti àwọn tí wọ́n kú ikú ogun sàn ju àwọn tí wọ́n kú ikú ebi lọ,àwọn tí ebi pa joró dójú ikú,nítorí àìsí oúnjẹ ninu oko.

10. Àwọn obinrin tí wọn ní ojú àánú ti fi ọwọ́ ara wọn se ọmọ wọn jẹ,wọ́n fi ọmọ wọn ṣe oúnjẹ jẹ,nígbà tí ìparun dé bá àwọn eniyan mi.

11. OLUWA bínú gidigidi,ó tú ibinu gbígbóná rẹ̀ jáde.OLUWA dá iná kan ní Sioni tí ó jó ìpìlẹ̀ rẹ̀ run.

12. Àwọn ọba ayé kò gbàgbọ́,bẹ́ẹ̀ ni gbogbo aráyé kò gbà pé ó lè ṣẹlẹ̀,pé ọ̀tá lè wọ ẹnubodè Jerusalẹmu.

Ka pipe ipin Ẹkún Jeremaya 4