Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkún Jeremaya 2:9-22 BIBELI MIMỌ (BM)

9. Àwọn ẹnubodè rẹ̀ ti rì, wọ́n ti wọlẹ̀;ó ti ṣẹ́ àwọn ọ̀pá ìdábùú ìlẹ̀kùn bodè;ọba rẹ̀ ati àwọn olórí rẹ̀ wà láàrin àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn;òfin kò sí mọ́, àwọn wolii rẹ̀ kò sì ríran láti ọ̀dọ̀ OLUWA mọ́.

10. Àwọn àgbààgbà Sioni jókòó lórí ilẹ̀, wọ́n dákẹ́ rọ́rọ́,wọ́n ku eruku sórí,wọ́n sì wọ aṣọ ọ̀fọ̀.Àwọn ọmọbinrin Jerusalẹmu doríkodò.

11. Ẹkún sísun ti sọ ojú mi di bàìbàì,ìdààmú bá ọkàn mi;ìbànújẹ́ sì mú kí ó rẹ̀wẹ̀sìnítorí ìparun àwọn eniyan mi,nítorí pé àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ati àwọn ọmọ ọwọ́ ń dákú lójú pópó láàrin ìlú.

12. Bí wọ́n ti ń dákú láàrin ìlú,bí ẹni tí a ṣá lọ́gbẹ́,tí wọ́n sì ń kú lọ lẹ́yìn ìyá wọn,wọ́n ń sọkún sí àwọn ìyá wọn pé:“Ebi ń pa wá, òùngbẹ sì ń gbẹ wá.”

13. Kí ni mo lè sọ nípa rẹ,kí sì ni ǹ bá fi ọ́ wé, Jerusalẹmu?Kí ni mo lè fi wé ọ,kí n lè tù ọ́ ninu, ìwọ Sioni?Nítorí bí omi òkun ni ìparun rẹ gbòòrò;ta ló lè mú ọ pada bọ̀ sípò?

14. Ìran èké ati ti ẹ̀tàn ni àwọn wolii rẹ ń rí sí ọ;wọn kò fi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ hàn ọ́,kí wọ́n lè dá ire rẹ pada,ṣugbọn wọ́n ń ríran èké ati ìran ẹ̀tàn sí ọ.

15. Gbogbo àwọn tí ń rékọjá lọń pàtẹ́wọ́ lé ọ lórí,wọ́n ń pòṣé,wọ́n sì ń mi orí wọn sí ọ, Jerusalẹmu.Wọ́n ń sọ pé:“Ṣé ìlú yìí ni à ń pè níìlú tí ó lẹ́wà jùlọ,tí ó jẹ́ ayọ̀ gbogbo ayé?”

16. Gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ ń fi ọ́ ṣẹ̀sín,wọ́n ń pòṣé,wọ́n ń fi ọ́ ṣe ẹlẹ́yà.Wọ́n ń wí pé:“A ti pa á run!Ọjọ́ tí a tí ń retí nìyí;ọwọ́ wa ti tẹ Jerusalẹmu wàyí!A ti rí ohun tí à ń wá!”

17. OLUWA ti ṣe bí ó ti pinnu,ó ti mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ,bí ó ti sọ ní ìgbà àtijọ́.Ó ti wó ọ lulẹ̀ láìṣàánú rẹ;ó ti jẹ́ kí ọ̀tá yọ̀ ọ́,ó ti fún àwọn ọ̀tá rẹ ni agbára kún agbára.

18. Ẹ kígbe sí OLUWA,ẹ̀yin ará Sioni!Ẹ jẹ́ kí omi máa dà lójú yín pòròpòrò tọ̀sán-tòru;ẹ má sinmi,ẹ má sì jẹ́ kí oorun kùn yín.

19. Ẹ dìde, ẹ kígbe lálẹ́,ní àkókò tí àwọn aṣọ́de ń bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́!Ẹ tú ẹ̀dùn ọkàn yín jáde bí omi níwájú OLUWA!Ẹ gbé ọwọ́ ẹ̀bẹ̀ sókè sí i,nítorí ẹ̀mí àwọn ọmọ yín tí ebi ń pa kú lọ ní gbogbo ìkóríta.

20. Wò ó! OLUWA,ṣe akiyesi ohun tí ń ṣẹlẹ̀!Wo àwọn tí ò ń ṣe irú èyí sí!Ṣé ó yẹ kí àwọn obinrin máa jẹ ọmọ wọn?Ọmọ ọwọ́ tí wọn ń tọ́jú!Ṣé ó yẹ kí á pa alufaa ati wolii, ní ibi mímọ́ OLUWA?

21. Àtàwọn ọ̀dọ́, àtàwọn arúgbówọ́n kú kalẹ̀ lọ lójú pópó,àtàwọn ọdọmọbinrin, àtàwọn ọdọmọkunrin mi,gbogbo wọn ni idà ti pa.Ní ọjọ́ ibinu rẹ ni o pa wọ́n,o pa wọ́n ní ìpakúpa láìṣàánú wọn.

22. O pe àwọn ọ̀tá mi jọ sí mibí ẹni peniyan síbi àjọ̀dún;kò sì sí ẹni tí ó yèní ọjọ́ ibinu rẹ, OLUWA.Ọ̀tá mi pa àwọn ọmọ mi run,àwọn tí mo tọ́, tí mo sì fẹ́ràn.

Ka pipe ipin Ẹkún Jeremaya 2