Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkún Jeremaya 1:6-15 BIBELI MIMỌ (BM)

6. Gbogbo ògo Jerusalẹmu ti fò lọ kúrò lára rẹ̀,àwọn olórí rẹ̀ dàbí àgbọ̀nríntí kò rí koríko tútù jẹ;agbára kò sí fún wọn mọ́,wọ́n ń sálọ níwájú àwọn tí ń lé wọn.

7. Ní ọjọ́ ìpọ́njú ati ìbànújẹ́,Jerusalẹmu ranti àwọn nǹkan iyebíye tí ó ní ní ìgbà àtijọ́.Nígbà tí àwọn eniyan rẹ̀ bọ́ sọ́wọ́ ọ̀tá,tí kò sì sí ẹni tí yóo ràn wọ́n lọ́wọ́.Àwọn ọ̀tá bẹ̀rẹ̀ sí yọ̀ ọ́,wọ́n sì ń fi ṣẹ̀sín nítorí ìṣubú rẹ̀.

8. Jerusalẹmu ti dẹ́ṣẹ̀ burúkú,nítorí náà ó ti di eléèérí.Àwọn tí wọn ń bu ọlá fún un tẹ́lẹ̀ ti ń kẹ́gàn rẹ̀,nítorí pé wọ́n ti rí ìhòòhò rẹ̀.Òun pàápàá ń kérora, ó sì fi ojú pamọ́.

9. Ìwà èérí rẹ̀ hàn níbi ìṣẹ́tí aṣọ rẹ̀,kò sì bìkítà fún ìparun tí ń bọ̀.Nítorí náà ni ìṣubú rẹ̀ fi pọ̀, tí kò sì fi ní olùtùnú.Ó ké pe OLUWA pé kí ó ṣíjú wo ìnira òun,nítorí pé ọ̀tá ti borí rẹ̀.

10. Ọ̀tá ti tọwọ́ bọ ilé ìṣúra rẹ̀,wọ́n sì ti kó gbogbo nǹkan iyebíye inú rẹ̀ lọ;ó ń wo àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn,tí wọn ń wọ ibi mímọ́ rẹ̀.Àwọn tí ó pàṣẹ péwọn kò gbọdọ̀ dé àwùjọ àwọn eniyan rẹ̀.

11. Gbogbo àwọn eniyan rẹ̀ ń kérorabí wọ́n ti ń wá oúnjẹ;wọ́n ń fi ìṣúra wọn ṣe pàṣípààrọ̀ fún oúnjẹkí wọ́n baà lè lágbára.Jerusalẹmu ń sunkún pé,“Bojúwò mí, OLUWA,nítorí pé mo di ẹni ẹ̀gàn.”

12. Ó ní, “Ṣé ọ̀rọ̀ yìí kò kàn yín ni,gbogbo ẹ̀yin tí ẹ̀ ń kọjá lọ?Ẹ̀yin náà ẹ wò ó, kí ẹ ṣe akiyesi rẹ̀,bóyá ìbànújẹ́ kan wàtí ó dàbí èyí tí ó dé bá mi yìí;tí OLUWA mú kí ó dé bá mi,ní ọjọ́ ibinu gbígbóná rẹ̀.

13. “Ó rán iná láti òkè ọ̀run wá;ó dá a sí egungun mi;ó dẹ àwọ̀n sílẹ̀ fún mi;ó sì dá mi pada.Mo dàbí odi,mo sì fi ìgbà gbogbo dákú.

14. “Ó di ẹ̀ṣẹ̀ mi bí àjàgà,ó gbé e kọ́ mi lọ́rùn,ó sì sọ mí di aláìlágbára.OLUWA ti fi mí léàwọn tí n kò lè dojú kọ lọ́wọ́.

15. “OLUWA ti fi ẹsẹ̀ tẹ àwọn akọni mi mọ́lẹ̀;ó pe ọpọlọpọ eniyan jọ sí mi,ó ní kí wọ́n pa àwọn ọdọmọkunrin mi;OLUWA ti tẹ àwọn ọmọ Juda ní àtẹ̀rẹ́,bí ẹni tẹ èso àjàrà fún ọtí waini.

Ka pipe ipin Ẹkún Jeremaya 1