Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkisodu 8:4-17 BIBELI MIMỌ (BM)

4. Àwọn ọ̀pọ̀lọ́ náà yóo máa fò mọ́ ìwọ, ati àwọn eniyan rẹ ati àwọn ẹmẹ̀wà rẹ.” ’ ”

5. OLUWA rán Mose pé, “Sọ fún Aaroni pé kí ó na ọwọ́ rẹ̀ ati ọ̀pá rẹ̀ sórí àwọn odò ati àwọn adágún tí wọ́n gbẹ́, ati sórí gbogbo ibi tí omi dárogún sí, kí àwọn ọ̀pọ̀lọ́ lè jáde sórí ilẹ̀ Ijipti.”

6. Aaroni bá na ọwọ́ rẹ̀ sí orí gbogbo omi ilẹ̀ Ijipti, ọ̀pọ̀lọ́ bá wọ́ jáde, wọ́n sì bo gbogbo ilẹ̀ Ijipti.

7. Àwọn pidánpidán náà ṣe bẹ́ẹ̀ pẹlu ọgbọ́n idán wọn, wọ́n mú kí ọ̀pọ̀lọ́ bo ilẹ̀ Ijipti.

8. Nígbà náà ni Farao pe Mose ati Aaroni, ó ní, “Ẹ bẹ OLUWA kí ó kó ọ̀pọ̀lọ́ kúrò lọ́dọ̀ èmi ati àwọn eniyan mi, n óo sì jẹ́ kí àwọn ará Israẹli lọ rúbọ sí OLUWA.”

9. Mose dá Farao lóhùn pé, “Sọ ìgbà tí o fẹ́ kí n gbadura fún ìwọ ati àwọn ẹmẹ̀wà rẹ, ati àwọn eniyan rẹ, kí Ọlọrun lè run gbogbo àwọn ọ̀pọ̀lọ́ tí wọ́n wà lọ́dọ̀ yín, ati ninu ilé yín; kí ó sì jẹ́ pé kìkì odò Naili nìkan ni ọ̀pọ̀lọ́ yóo kù sí.”

10. Ọba dáhùn pé, “Ní ọ̀la.”Mose bá wí pé, “Bí o ti wí gan-an ni yóo rí, kí o lè mọ̀ pé kò sí ẹlòmíràn tí ó dàbí OLUWA Ọlọrun wa.

11. Àwọn ọ̀pọ̀lọ́ náà yóo kúrò lọ́dọ̀ rẹ, ati ninu àwọn ilé rẹ, ati lọ́dọ̀ àwọn ẹmẹ̀wà rẹ, ati lọ́dọ̀ àwọn eniyan rẹ; kìkì odò Naili nìkan ni ọ̀pọ̀lọ́ yóo kù sí.”

12. Mose ati Aaroni bá jáde kúrò níwájú Farao, Mose gbadura sí OLUWA pé kí ó mú àwọn ọ̀pọ̀lọ́ náà kúrò, gẹ́gẹ́ bí òun ati Farao ti jọ ṣe àdéhùn.

13. OLUWA ṣe ohun tí Mose fi adura bèèrè, àwọn ọ̀pọ̀lọ́ tí wọ́n wà ninu gbogbo ilé, ati ní àgbàlá, ati ní gbogbo oko sì kú.

14. Wọ́n kó wọn jọ ní òkítì òkítì, gbogbo ìlú sì bẹ̀rẹ̀ sí rùn.

15. Nígbà tí Farao rí i pé gbogbo ọ̀pọ̀lọ́ náà kú tán, ọkàn rẹ̀ tún le, kò sì ṣe ohun tí Mose ati Aaroni wí mọ́, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti sọ tẹ́lẹ̀.

16. OLUWA rán Mose pé, kí ó sọ fún Aaroni pé kí ó na ọ̀pá rẹ̀ jáde, kí ó sì fi lu erùpẹ̀ ilẹ̀, kí gbogbo rẹ̀ sì di iná orí ní gbogbo ilẹ̀ Ijipti.

17. Wọ́n ṣe bí OLUWA ti wí; Aaroni na ọ̀pá ọwọ́ rẹ̀, ó fi lu erùpẹ̀ ilẹ̀, iná sì bo àwọn eniyan ati àwọn ẹranko; gbogbo erùpẹ̀ ilẹ̀ sì di iná ní gbogbo ilẹ̀ Ijipti.

Ka pipe ipin Ẹkisodu 8