Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkisodu 8:22-32 BIBELI MIMỌ (BM)

22. Ṣugbọn ní ọjọ́ náà, èmi OLUWA yóo ya ilẹ̀ Goṣeni sọ́tọ̀, níbi tí àwọn eniyan mi ń gbé, kí ọ̀wọ́ eṣinṣin má baà lè débẹ̀, kí ẹ lè mọ̀ pé èmi ni OLUWA ní ayé yìí.

23. Bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe fi ààlà sí ààrin àwọn eniyan mi ati àwọn eniyan rẹ̀. Ní ọ̀la ni iṣẹ́ ìyanu náà yóo ṣẹ.”

24. OLUWA ṣe bẹ́ẹ̀; ọ̀wọ́ eṣinṣin wọ inú ilé Farao ati ti àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ ati gbogbo ilẹ̀ àwọn ará Ijipti. Eṣinṣin sì ba ilẹ̀ náà jẹ́.

25. Farao bá pe Mose ati Aaroni, ó ní, “Ẹ lọ rúbọ sí Ọlọrun yín, ṣugbọn ní ilẹ̀ yìí ni kí ẹ ti rú u.”

26. Mose dá a lóhùn pé, “Kò ní tọ̀nà bí a bá ṣe bẹ́ẹ̀; nítorí pé àwọn nǹkan mìíràn lè wà ninu ohun tí a óo fi rúbọ sí OLUWA Ọlọrun wa tí ó lè jẹ́ ìríra fún àwọn ará Ijipti. Bí a bá fi ohunkohun rúbọ tí ó jẹ́ ìríra lójú àwọn ará Ijipti, ṣé wọn kò ní sọ wá ní òkúta pa?

27. A níláti lọ sinu aṣálẹ̀ ní ìrìn ọjọ́ mẹta kí á sì rúbọ sí OLUWA Ọlọrun wa gẹ́gẹ́ bí ó ti pa á láṣẹ fún wa.”

28. Farao dáhùn, ó ní, “N óo fún yín láàyè láti lọ rúbọ sí OLUWA Ọlọrun yín ninu aṣalẹ̀, ṣugbọn ẹ kò gbọdọ̀ lọ jìnnà; ati pé, mo fẹ́ kí ẹ bá mi bẹ Ọlọrun yín.”

29. Mose bá dáhùn pé, “Wò ó, ń óo jáde kúrò ní iwájú rẹ nisinsinyii, n óo sì lọ gbadura sí OLUWA, kí ọ̀wọ́ eṣinṣin wọnyi lè lọ kúrò lọ́dọ̀ rẹ ní ọ̀la, kí wọ́n sì kúrò lọ́dọ̀ àwọn ẹmẹ̀wà rẹ ati àwọn eniyan rẹ pẹlu ṣugbọn kí Farao má tún dalẹ̀, kí ó má wí pé àwọn eniyan Israẹli kò gbọdọ̀ lọ rúbọ sí OLUWA.”

30. Mose bá jáde kúrò níwájú Farao, ó lọ gbadura sí OLUWA,

31. OLUWA sì ṣe ohun tí Mose bèèrè, ó mú kí ọ̀wọ́ eṣinṣin náà kúrò lọ́dọ̀ Farao ati àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ ati àwọn eniyan rẹ̀. Ó mú kí gbogbo eṣinṣin náà kúrò láìku ẹyọ kan.

32. Ṣugbọn ọkàn Farao tún le, kò sì jẹ́ kí àwọn eniyan náà lọ.

Ka pipe ipin Ẹkisodu 8