Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkisodu 8:11-22 BIBELI MIMỌ (BM)

11. Àwọn ọ̀pọ̀lọ́ náà yóo kúrò lọ́dọ̀ rẹ, ati ninu àwọn ilé rẹ, ati lọ́dọ̀ àwọn ẹmẹ̀wà rẹ, ati lọ́dọ̀ àwọn eniyan rẹ; kìkì odò Naili nìkan ni ọ̀pọ̀lọ́ yóo kù sí.”

12. Mose ati Aaroni bá jáde kúrò níwájú Farao, Mose gbadura sí OLUWA pé kí ó mú àwọn ọ̀pọ̀lọ́ náà kúrò, gẹ́gẹ́ bí òun ati Farao ti jọ ṣe àdéhùn.

13. OLUWA ṣe ohun tí Mose fi adura bèèrè, àwọn ọ̀pọ̀lọ́ tí wọ́n wà ninu gbogbo ilé, ati ní àgbàlá, ati ní gbogbo oko sì kú.

14. Wọ́n kó wọn jọ ní òkítì òkítì, gbogbo ìlú sì bẹ̀rẹ̀ sí rùn.

15. Nígbà tí Farao rí i pé gbogbo ọ̀pọ̀lọ́ náà kú tán, ọkàn rẹ̀ tún le, kò sì ṣe ohun tí Mose ati Aaroni wí mọ́, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti sọ tẹ́lẹ̀.

16. OLUWA rán Mose pé, kí ó sọ fún Aaroni pé kí ó na ọ̀pá rẹ̀ jáde, kí ó sì fi lu erùpẹ̀ ilẹ̀, kí gbogbo rẹ̀ sì di iná orí ní gbogbo ilẹ̀ Ijipti.

17. Wọ́n ṣe bí OLUWA ti wí; Aaroni na ọ̀pá ọwọ́ rẹ̀, ó fi lu erùpẹ̀ ilẹ̀, iná sì bo àwọn eniyan ati àwọn ẹranko; gbogbo erùpẹ̀ ilẹ̀ sì di iná ní gbogbo ilẹ̀ Ijipti.

18. Àwọn pidánpidán náà gbìyànjú láti mú kí iná jáde pẹlu ọgbọ́n idán wọn, ṣugbọn wọn kò lè ṣe é. Iná bo gbogbo eniyan ati àwọn ẹranko.

19. Àwọn pidánpidán náà sọ fún Farao pé, “Iṣẹ́ Ọlọrun ni èyí.” Ṣugbọn ọkàn Farao le, kò sì fetí sí ọ̀rọ̀ wọn gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti sọ tẹ́lẹ̀.

20. OLUWA bá tún sọ fún Mose pé, “Dìde ní òwúrọ̀ kutukutu, kí o lọ dúró de ọba Farao bí ó bá ti ń jáde lọ sétí odò, wí fún un pé, kí ó gbọ́ ohun tí èmi OLUWA wí, pé kí ó jẹ́ kí àwọn eniyan mi lọ sìn mí.

21. Wí fún un pé, mo ní, tí kò bá jẹ́ kí wọ́n lọ n óo da eṣinṣin bo òun ati àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ ati àwọn eniyan rẹ̀, àwọn ará ilé rẹ̀ ati ti àwọn ará Ijipti, orí ilẹ̀ tí wọ́n dúró lé yóo sì kún fún ọ̀wọ́ eṣinṣin.

22. Ṣugbọn ní ọjọ́ náà, èmi OLUWA yóo ya ilẹ̀ Goṣeni sọ́tọ̀, níbi tí àwọn eniyan mi ń gbé, kí ọ̀wọ́ eṣinṣin má baà lè débẹ̀, kí ẹ lè mọ̀ pé èmi ni OLUWA ní ayé yìí.

Ka pipe ipin Ẹkisodu 8