Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkisodu 5:3-15 BIBELI MIMỌ (BM)

3. Wọ́n dá a lóhùn pé, “Ọlọrun àwọn Heberu ni ó farahàn wá; jọ̀wọ́, fún wa ní ààyè láti lọ sí aṣálẹ̀ ní ìwọ̀n ìrìn ọjọ́ mẹta, kí á lè lọ rúbọ sí OLUWA Ọlọrun wa, kí ó má baà fi àjàkálẹ̀ àrùn tabi ogun bá wa jà.”

4. Ṣugbọn ọba Ijipti dá wọn lóhùn pé, “Ìwọ Mose ati ìwọ Aaroni, kí ló dé tí ẹ fi kó àwọn eniyan wọnyi kúrò lẹ́nu iṣẹ́ wọn? Ẹ kó wọn pada kíákíá.”

5. Farao fi kún un pé, “Ṣé ẹ̀yin náà rí i pé àwọn eniyan yìí pọ̀ pupọ ju àwọn ọmọ-ìbílẹ̀ ilẹ̀ yìí lọ, ẹ sì tún kó wọn kúrò lẹ́nu iṣẹ́ wọn?”

6. Ní ọjọ́ náà gan-an ni Farao pàṣẹ fún gbogbo àwọn ọ̀gá tí wọn ń kó àwọn ọmọ Israẹli ṣiṣẹ́ pé,

7. “Ẹ kò gbọdọ̀ fún àwọn eniyan wọnyi ní koríko láti fi ṣe bíríkì bí ẹ ti ṣe ń fún wọn tẹ́lẹ̀ mọ; ẹ jẹ́ kí wọn máa lọ kó koríko fúnra wọn.

8. Iye bíríkì tí wọn ń ṣe tẹ́lẹ̀ kò sì gbọdọ̀ dín; nítorí pé nígbà tí iṣẹ́ kò ká wọn lára ni wọ́n ṣe ń rí ààyè pariwo pé, ‘Ẹ jẹ́ kí á lọ rúbọ sí Ọlọrun wa.’

9. Ẹ fi iṣẹ́ kún iṣẹ́ wọn. Nígbà tí iṣẹ́ bá wọ̀ wọ́n lọ́rùn gan-an, bí ẹnikẹ́ni bá tilẹ̀ ń parọ́ fún wọn, wọn kò ní fetí sí i.”

10. Àwọn tí wọn ń kó àwọn ọmọ Israẹli ṣiṣẹ́ bá jáde tọ̀ wọ́n lọ, wọ́n sọ fún wọn pé, “Ẹ gbọ́ bí Farao ti wí; ó ní òun kò ní fún yín ní koríko mọ́.

11. Ó ní kí ẹ lọ máa wá koríko fúnra yín níbikíbi tí ẹ bá ti rí. Ṣugbọn iye bíríkì tí ẹ̀ ń mọ tẹ́lẹ̀ kò gbọdọ̀ dín!”

12. Wọ́n bá fọ́n káàkiri gbogbo ilẹ̀ Ijipti láti wá àgékù koríko.

13. Àwọn tí wọn ń kó wọn ṣiṣẹ́ a máa fi ipá mú wọn pé, lojumọ, wọ́n gbọdọ̀ mọ iye bíríkì tí wọ́n máa ń mọ tẹ́lẹ̀, nígbà tí wọn kò tíì máa wá koríko fúnra wọn.

14. Àwọn akóniṣiṣẹ́ Farao bẹ̀rẹ̀ sí na àwọn tí wọ́n fi ṣe olórí láàrin àwọn ọmọ Israẹli. Wọn á máa bi wọ́n pé “Kí ló dé tí bíríkì tí ẹ mọ lónìí kò fi tó iye tí ó yẹ kí ẹ mọ?”

15. Àwọn tí wọ́n fi ṣe olórí láàrin àwọn ọmọ Israẹli bá ké tọ Farao lọ, wọ́n ní, “Kí ló dé tí o fi ń ṣe báyìí sí àwa iranṣẹ rẹ?

Ka pipe ipin Ẹkisodu 5