Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkisodu 5:16-23 BIBELI MIMỌ (BM)

16. Ẹnikẹ́ni kò fún wa ní koríko, sibẹ wọ́n ní dandan, a gbọdọ̀ mọ iye bíríkì tí à ń mọ tẹ́lẹ̀. Wọ́n ń lù wá, bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ará Ijipti gan-an ni wọ́n jẹ̀bi ọ̀rọ̀ náà.”

17. Ṣugbọn Farao dá wọn lóhùn pé, “Ọ̀lẹ ni yín, ẹ kò fẹ́ ṣiṣẹ́ ni ẹ fi ń sọ pé kí n jẹ́ kí ẹ lọ rúbọ sí OLUWA.

18. Ẹ kúrò níwájú mi nisinsinyii, kí ẹ lọ máa ṣiṣẹ́ yín; kò sí ẹni tí yóo fún yín ní koríko, iye bíríkì tí ẹ̀ ń mọ tẹ́lẹ̀ kò sì gbọdọ̀ dín.”

19. Àwọn tí wọ́n jẹ́ olórí láàrin àwọn ọmọ Israẹli rí i pé àwọn wà ninu ewu, nígbà tí wọ́n gbọ́ pé iye bíríkì tí àwọn ń mọ lojumọ kò gbọdọ̀ dín rárá.

20. Bí wọ́n ti ń ti ọ̀dọ̀ Farao bọ̀, wọ́n lọ sọ́dọ̀ Mose ati Aaroni tí wọ́n dúró dè wọ́n, wọ́n sì sọ fún wọn pé,

21. “Ọlọrun ni yóo dájọ́ fún yín, ẹ̀yin tí ẹ sọ wá di ẹni ìríra níwájú Farao ati àwọn iranṣẹ rẹ̀, ẹ sì ti yọ idà lé wọn lọ́wọ́ kí wọ́n fi pa wá.”

22. Mose bá tún yipada sí OLUWA, ó ní, “OLUWA, kí ló dé tí o fi ṣe ibi sí àwọn eniyan wọnyi? Kí ló dé tí o fi rán mi sí wọn?

23. Nítorí pé, láti ìgbà tí mo ti lọ sí ọ̀dọ̀ Farao láti bá a sọ̀rọ̀ ní orúkọ rẹ, ni ó ti ń ṣe àwọn eniyan wọnyi níbi, bẹ́ẹ̀ ni o kò sì gba àwọn eniyan rẹ sílẹ̀ rárá!”

Ka pipe ipin Ẹkisodu 5