Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkisodu 35:11-21 BIBELI MIMỌ (BM)

11. àgọ́ àjọ, ati àwọn ìbòrí rẹ, àwọn ìkọ́ rẹ̀ ati àwọn àkànpọ̀ igi rẹ̀, àwọn ọ̀pá rẹ̀, àwọn òpó rẹ̀, ati àwọn ìtẹ́lẹ̀ wọn.

12. Àpótí ẹ̀rí, ati àwọn ọ̀pá rẹ̀, ìtẹ́ àánú rẹ̀, ati aṣọ títa rẹ̀.

13. Tabili, pẹlu àwọn ọ̀pá rẹ̀ ati gbogbo àwọn ohun èlò rẹ̀ pẹlu burẹdi ìfihàn orí rẹ̀.

14. Ọ̀pá fìtílà fún iná títàn, ati àwọn ohun èlò tí ó jẹ mọ́ fìtílà rẹ̀ ati òróró fún iná títàn.

15. Pẹpẹ turari, ati àwọn ọ̀pá rẹ̀ ati òróró ìyàsímímọ́, ati turari olóòórùn dídùn, ati àwọn aṣọ títa fún ẹnu ọ̀nà àgọ́ náà.

16. Pẹpẹ ẹbọ sísun tòun ti ojú ààrò onídẹ rẹ̀, pẹlu àwọn ọ̀pá rẹ̀ ati àwọn ohun èlò tí ó jẹ mọ́ ti pẹpẹ ẹbọ, agbada omi ati ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀.

17. Àwọn aṣọ títa ti àgbàlá ati àwọn òpó rẹ̀ ati ìtẹ́lẹ̀ àwọn òpó ati aṣọ títa fún ẹnu ọ̀nà àgbàlá náà.

18. Àwọn èèkàn àgọ́, ati àwọn èèkàn àgbàlá pẹlu àwọn okùn wọn;

19. àwọn aṣọ tí wọ́n ṣe iṣẹ́ ọnà sí fún ṣíṣe iṣẹ́ alufaa níbi mímọ́, ati àwọn ẹ̀wù mímọ́ fún Aaroni alufaa, ati ẹ̀wù iṣẹ́ àwọn ọmọ rẹ̀, tí wọn yóo máa fi ṣe iṣẹ́ alufaa.”

20. Gbogbo àwọn ọmọ Israẹli bá túká lọ́dọ̀ Mose.

21. Lẹ́yìn náà gbogbo àwọn tí ọ̀rọ̀ náà wọ̀ lọ́kàn, tí ó sì jẹ lógún bẹ̀rẹ̀ sí pada wá ní ọ̀kọ̀ọ̀kan, wọn ń mú ọrẹ wá fún kíkọ́ àgọ́ àjọ náà, ati gbogbo ohun tí wọn nílò fún àgọ́ náà, ati fún ẹ̀wù mímọ́ àwọn alufaa.

Ka pipe ipin Ẹkisodu 35