Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkisodu 34:11-18 BIBELI MIMỌ (BM)

11. “Máa pa àwọn òfin tí mo fún ọ lónìí yìí mọ́. N óo lé àwọn ará Hamori ati àwọn ará Kenaani, àwọn ará Hiti ati àwọn ará Perisi, àwọn ará Hifi ati àwọn ará Jebusi, jáde kúrò níwájú rẹ.

12. Ẹ ṣọ́ra gidigidi, kí ẹ rí i pé ẹ kò bá àwọn tí wọn ń gbé ilẹ̀ tí ẹ̀ ń lọ dá majẹmu kankan, kí wọn má baà dàbí tàkúté tí a dẹ sí ààrin yín.

13. Ṣugbọn, ẹ wó gbogbo pẹpẹ wọn, kí ẹ sì fọ́ gbogbo àwọn ère wọn, kí ẹ sì gé gbogbo igbó oriṣa wọn lulẹ̀.

14. “Ẹ kò gbọdọ̀ bọ oriṣa, nítorí èmi OLUWA, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ owú, Ọlọrun tíí máa jowú ni mí.

15. Ẹ kò gbọdọ̀ bá ẹnikẹ́ni dá majẹmu ninu gbogbo àwọn eniyan tí ń gbé ilẹ̀ náà, kí ẹ má baà bá wọn dá majẹmu tán, kí ó wá di pé, nígbà tí wọn bá ń rúbọ sí oriṣa wọn, tí wọn sì ń ṣe ìṣekúṣe nídìí oriṣa wọn, wọn óo máa pè yín, pé kí ẹ máa lọ bá wọn jẹ ninu ẹbọ wọn.

16. Kó má baà wá di pé ẹ̀ ń fẹ́mọ lọ́wọ́ wọn fún àwọn ọmọkunrin yín, kí àwọn ọmọbinrin yín má baà máa ṣe ìṣekúṣe nídìí oriṣa, kí wọ́n sì mú kí àwọn ọmọkunrin yín náà máa ṣe ìṣekúṣe nídìí oriṣa wọn.

17. “Ẹ kò gbọdọ̀ yá ère fún ara yín.

18. “Ẹ gbọdọ̀ máa ṣe àjọ àìwúkàrà, burẹdi tí kò ní ìwúkàrà ni ẹ gbọdọ̀ máa jẹ fún ọjọ́ meje ní àkókò àjọ náà, ninu oṣù Abibu, gẹ́gẹ́ bí mo ti pàṣẹ fún yín, nítorí pé ninu oṣù Abibu ni ẹ jáde ní ilẹ̀ Ijipti.

Ka pipe ipin Ẹkisodu 34