Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkisodu 32:28-35 BIBELI MIMỌ (BM)

28. Àwọn ọmọ Lefi sì ṣe gẹ́gẹ́ bí Mose ti wí, àwọn tí wọ́n kú láàrin àwọn eniyan náà tó ẹgbẹẹdogun (3,000) ọkunrin.

29. Mose bá wí fún wọn pé, “Lónìí ni ẹ yan ara yín fún iṣẹ́ OLUWA, olukuluku yín sì ti fi ẹ̀mí ọmọ rẹ̀, ati ti arakunrin rẹ̀ yan ara rẹ̀, kí ó lè tú ibukun rẹ̀ sí orí yín lónìí yìí.”

30. Ní ọjọ́ keji, Mose wí fún àwọn eniyan náà pé, “Ẹ ti dẹ́ṣẹ̀ ńlá, n óo tún gòkè tọ OLUWA lọ, bóyá n óo lè ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ yín.”

31. Mose bá pada tọ OLUWA lọ, ó ní, “Yéè! Àwọn eniyan wọnyi ti dẹ́ṣẹ̀ ńlá; wọ́n ti fi wúrà yá ère fún ara wọn;

32. ṣugbọn OLUWA, jọ̀wọ́, dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, pa orúkọ mi rẹ́ patapata kúrò ninu ìwé tí o kọ orúkọ àwọn eniyan rẹ sí.”

33. OLUWA bá dá Mose lóhùn pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá dẹ́ṣẹ̀ sí mi ni n óo pa orúkọ rẹ̀ rẹ́ kúrò ninu ìwé mi.

34. Pada lọ nisinsinyii, kí o sì kó àwọn eniyan náà lọ sí ibi tí mo sọ fún ọ. Ranti pé angẹli mi yóo máa ṣáájú yín lọ, ṣugbọn ọjọ́ ń bọ̀, tí n óo jẹ àwọn eniyan náà níyà nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn.”

35. Nítorí náà, nígbà tó yá, Ọlọrun rán àjàkálẹ̀ àrùn burúkú kan sáàrin àwọn eniyan náà, nítorí pé wọ́n mú kí Aaroni fi wúrà yá ère mààlúù fún wọn.

Ka pipe ipin Ẹkisodu 32