Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkisodu 32:25-33 BIBELI MIMỌ (BM)

25. Nígbà tí Mose rí i pé Aaroni ti dá rúdurùdu sílẹ̀, láàrin àwọn eniyan náà, ati pé apá kò ká wọn mọ́, ọ̀rọ̀ náà sì sọ wọ́n di ẹni ìtìjú níwájú àwọn ọ̀tá wọn,

26. Mose bá dúró ní ẹnu ọ̀nà àgọ́, ó ní, “Ẹ̀yin wo ni ẹ̀ ń ṣe ti OLUWA, ẹ máa bọ̀ lọ́dọ̀ mi.” Gbogbo àwọn ọmọ Lefi bá kóra jọ sọ́dọ̀ rẹ̀.

27. Mose wí fún wọn pé, “Ẹ gbọ́ bí OLUWA Ọlọrun Israẹli ti wí, ó ní, ‘Gbogbo ẹ̀yin ọkunrin, ẹ sán idà yín mọ́ ẹ̀gbẹ́ yín kí ẹ sì máa lọ láti ẹnu ọ̀nà dé ẹnu ọ̀nà, jákèjádò ibùdó, kí olukuluku máa pa arakunrin rẹ̀ ati ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, ati aládùúgbò rẹ̀.’ ”

28. Àwọn ọmọ Lefi sì ṣe gẹ́gẹ́ bí Mose ti wí, àwọn tí wọ́n kú láàrin àwọn eniyan náà tó ẹgbẹẹdogun (3,000) ọkunrin.

29. Mose bá wí fún wọn pé, “Lónìí ni ẹ yan ara yín fún iṣẹ́ OLUWA, olukuluku yín sì ti fi ẹ̀mí ọmọ rẹ̀, ati ti arakunrin rẹ̀ yan ara rẹ̀, kí ó lè tú ibukun rẹ̀ sí orí yín lónìí yìí.”

30. Ní ọjọ́ keji, Mose wí fún àwọn eniyan náà pé, “Ẹ ti dẹ́ṣẹ̀ ńlá, n óo tún gòkè tọ OLUWA lọ, bóyá n óo lè ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ yín.”

31. Mose bá pada tọ OLUWA lọ, ó ní, “Yéè! Àwọn eniyan wọnyi ti dẹ́ṣẹ̀ ńlá; wọ́n ti fi wúrà yá ère fún ara wọn;

32. ṣugbọn OLUWA, jọ̀wọ́, dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, pa orúkọ mi rẹ́ patapata kúrò ninu ìwé tí o kọ orúkọ àwọn eniyan rẹ sí.”

33. OLUWA bá dá Mose lóhùn pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá dẹ́ṣẹ̀ sí mi ni n óo pa orúkọ rẹ̀ rẹ́ kúrò ninu ìwé mi.

Ka pipe ipin Ẹkisodu 32