Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkisodu 30:1-13 BIBELI MIMỌ (BM)

1. “Fi igi akasia tẹ́ pẹpẹ kan, tí wọn yóo máa sun turari lórí rẹ̀.

2. Kí gígùn rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ kan, fífẹ̀ rẹ̀ yóo sì jẹ́ igbọnwọ kan. Ìbú ati òòró rẹ̀ yóo rí bákan náà, yóo sì ga ní igbọnwọ meji, àṣepọ̀ mọ́ ìwo rẹ̀ ni kí o ṣe é.

3. Fi ojúlówó wúrà bo òkè, ati gbogbo ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ yíká, ati ìwo rẹ̀ pẹlu. Fi wúrà ṣe ìgbátí yí gbogbo etí rẹ̀ po.

4. Lẹ́yìn náà, ṣe òrùka wúrà meji fún pẹpẹ náà, jó wọn mọ́ abẹ́ ìgbátí rẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ kinni keji, àwọn òrùka náà ni wọn yóo máa ti ọ̀pá bọ̀ nígbà tí wọ́n bá fẹ́ gbé pẹpẹ náà.

5. Fi igi akasia ṣe àwọn ọ̀pá, kí o sì yọ́ wúrà bò wọ́n.

6. Gbé e sílẹ̀ lóde aṣọ títa tí ó wà lẹ́bàá àpótí ẹ̀rí, lọ́gangan iwájú ìtẹ́ àánú tí ó wà lókè àpótí ẹ̀rí náà, níbi tí n óo ti máa ba yín pàdé.

7. Kí Aaroni máa sun turari olóòórùn dídùn lórí rẹ̀, ní àràárọ̀, nígbà tí ó bá ń tọ́jú àwọn fìtílà.

8. Nígbà tí ó bá ń gbé àwọn fìtílà náà sí ààyè wọn ní àṣáálẹ́, yóo máa sun turari náà pẹlu, títí lae ni yóo máa sun turari náà níwájú OLUWA ní ìrandíran yín.

9. Ẹ kò gbọdọ̀ sun turari tí ó jẹ́ aláìmọ́ lórí pẹpẹ náà, ẹ kò sì gbọdọ̀ sun ẹbọ sísun lórí rẹ̀; tabi ẹbọ oúnjẹ, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọdọ̀ ta ohun mímu sílẹ̀ fún ètùtù lórí rẹ̀.

10. Aaroni yóo máa ṣe ètùtù lórí àwọn ìwo rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan lọ́dún. Ẹ̀jẹ̀ ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ ni yóo máa fi ṣe ètùtù náà lórí rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan lọ́dún ní ìrandíran yín. Pẹpẹ náà yóo jẹ́ ohun èlò tí ó mọ́ jùlọ fún OLUWA.”

11. OLUWA sọ fún Mose pé,

12. “Nígbà tí o bá ka iye àwọn eniyan Israẹli, ẹnìkọ̀ọ̀kan gbọdọ̀ mú ohun ìràpadà ẹ̀mí rẹ̀ wá fún OLUWA, kí àjàkálẹ̀ àrùn má baà bẹ́ sílẹ̀ láàrin wọn, nígbà tí o bá kà wọ́n.

13. Ohun tí ẹnìkọ̀ọ̀kan tí o bá kà yóo san ni: ìdajì ṣekeli, tí a fi ìwọ̀n ilé OLUWA wọ̀n, (tí ó jẹ́ ogún ìwọ̀n gera fún ìwọ̀n ṣekeli kan), ìdajì ṣekeli náà yóo sì jẹ́ ti OLUWA.

Ka pipe ipin Ẹkisodu 30