Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkisodu 21:24-34 BIBELI MIMỌ (BM)

24. Bí ẹnìkan bá fọ́ eniyan lójú, kí wọ́n fọ́ ojú tirẹ̀ náà; bí ẹnìkan bá ká eniyan léyín, kí wọ́n ká eyín tirẹ̀ náà, bí ẹnìkan bá gé eniyan lọ́wọ́, kí wọ́n gé ọwọ́ tirẹ̀ náà, bí ẹnìkan bá gé eniyan lẹ́sẹ̀, kí wọ́n gé ẹsẹ̀ tirẹ̀ náà.

25. Bí ẹnìkan bá fi iná jó eniyan, kí wọ́n fi iná jó òun náà, bí ẹnìkan bá ṣá eniyan lọ́gbẹ́, kí wọ́n ṣá òun náà lọ́gbẹ́, bí ẹnìkan bá na eniyan lẹ́gba, kí wọ́n na òun náà lẹ́gba.

26. “Bí ẹnìkan bá gbá ẹrukunrin tabi ẹrubinrin rẹ̀ lójú, tí ojú náà sì fọ́, olúwarẹ̀ yóo dá ẹrú náà sílẹ̀ lọ́fẹ̀ẹ́ láìgba ohunkohun lọ́wọ́ rẹ̀, nítorí pé ó ti fọ́ ọ lójú.

27. Bí ó bá yọ eyín ẹrukunrin tabi ẹrubinrin rẹ̀, yóo dá ẹrú náà sílẹ̀ lọ́fẹ̀ẹ́, nítorí pé ó ti yọ ọ́ léyín.

28. “Bí mààlúù bá kan eniyan pa, kí wọ́n sọ mààlúù náà ní òkúta pa. Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ jẹ ẹran rẹ̀; ṣugbọn kí ẹnikẹ́ni má ṣe jẹ ẹni tí ó ni mààlúù náà níyà.

29. Ṣugbọn bí ó bá jẹ́ mààlúù náà ti kan eniyan tẹ́lẹ̀, tí wọ́n sì ti kìlọ̀ fún ẹni tí ó ni ín, tí kò sì so ó mọ́lẹ̀, bí ó bá pa eniyan, kí wọn sọ mààlúù náà ní òkúta pa, kí wọn sì pa ẹni tí ó ni ín pẹlu.

30. Ṣugbọn bí wọ́n bá gbà pé kí ẹni tí ó ni ín san owó ìtanràn, ó níláti san iyekíye tí wọ́n bá sọ pé kí ó san, kí ó baà lè ra ẹ̀mí ara rẹ̀ pada.

31. Bí irú mààlúù tí ó ti kan eniyan pa tẹ́lẹ̀ rí yìí bá tún kan ọmọ ẹnìkan pa, kì báà ṣe ọkunrin tabi obinrin, irú ẹ̀tọ́ kan náà tí a sọ yìí ni wọ́n gbọdọ̀ ṣe fún ẹni tí ó ni mààlúù náà.

32. Bí mààlúù náà bá kan ẹrú ẹnìkan pa, kì báà ṣe ẹrukunrin tabi ẹrubinrin, ẹni tí ó ni mààlúù náà níláti san ọgbọ̀n ṣekeli fadaka fún ẹni tí ó ni ẹrú tí mààlúù pa, kí wọ́n sì sọ mààlúù náà ní òkúta pa.

33. “Bí ẹnìkan bá gbẹ́ kòtò sílẹ̀, tí kò bá bò ó, tabi tí ó gbẹ́ kòtò tí kò sì dí i, bí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tabi mààlúù bá já sinu kòtò yìí, tí ó sì kú,

34. ẹni tí ó gbẹ́ kòtò yìí gbọdọ̀ san owó mààlúù tabi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà fún ẹni tí ó ni ín, òkú ẹran yìí yóo sì di ti ẹni tí ó gbẹ́ kòtò.

Ka pipe ipin Ẹkisodu 21