Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkisodu 21:2-7 BIBELI MIMỌ (BM)

2. Bí ẹnikẹ́ni bá ra Heberu kan lẹ́rú, ọdún mẹfa ni ẹrú náà óo fi sìn ín, ní ọdún keje, ó níláti dá a sílẹ̀ lọ́fẹ̀ẹ́ láìgba ohunkohun lọ́wọ́ rẹ̀.

3. Bí ó bá jẹ́ pé òun nìkan ni ó rà, òun nìkan ni òfin dá sílẹ̀, ṣugbọn bí ẹrú náà bá mú aya rẹ̀ lọ́wọ́ wá, bí ó bá ti ń dá a sílẹ̀, ó gbọdọ̀ dá aya rẹ̀ sílẹ̀ pẹlu.

4. Bí olówó rẹ̀ bá fẹ́ aya fún un, tí aya náà sì bímọ fún un, lọkunrin ati lobinrin, olówó rẹ̀ ni ó ni aya ati àwọn ọmọ patapata, òun nìkan ni òfin dá sílẹ̀.

5. Ṣugbọn bí ẹrú náà bá fúnra rẹ̀ wí ní gbangba pé òun fẹ́ràn olówó òun, ati aya òun, ati àwọn ọmọ òun, nítorí náà òun kò ní gba ìdásílẹ̀, kí òun má baà fi wọ́n sílẹ̀,

6. olówó rẹ̀ yóo mú un wá siwaju Ọlọrun, ní ibi ìlẹ̀kùn àgọ́ tabi òpó ìlẹ̀kùn, olówó rẹ̀ yóo fi òòlù lu ihò sí etí rẹ̀, ẹrú náà yóo sì di tirẹ̀ títí ayé.

7. “Bí ẹnìkan bá ta ọmọ rẹ̀ obinrin lẹ́rú, ẹrubinrin yìí kò ní jáde bí ẹrukunrin.

Ka pipe ipin Ẹkisodu 21