Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkisodu 17:7-16 BIBELI MIMỌ (BM)

7. Ó sì pe orúkọ ibẹ̀ ní Masa ati Meriba, nítorí ìwà ìka-ẹ̀sùn-síni-lẹ́sẹ̀ tí àwọn ọmọ Israẹli hù, ati nítorí dídán tí wọn dán OLUWA wò, wọ́n ní, “Ṣé OLUWA tún wà láàrin wa ni tabi kò sí mọ́?”

8. Lẹ́yìn èyí ni àwọn ará Amaleki wá, wọ́n sì bá àwọn ọmọ Israẹli jagun ní Refidimu.

9. Mose bá wí fún Joṣua pé, “Yan àwọn akọni ọkunrin láàrin yín kí o sì jáde lọ láti bá àwọn ará Amaleki jagun lọ́la, n óo dúró ní orí òkè pẹlu ọ̀pá Ọlọrun ní ọwọ́ mi.”

10. Joṣua ṣe bí Mose ti pàṣẹ fún un, ó bá àwọn ará Amaleki jagun. Mose ati Aaroni ati Huri bá gun orí òkè lọ.

11. Nígbà tí Mose bá gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè, àwọn ọmọ Israẹli a máa borí àwọn ará Amaleki, nígbà tí ó bá sì rẹ ọwọ́ sílẹ̀, àwọn ará Amaleki a máa borí àwọn ọmọ Israẹli.

12. Nígbà tí ó yá, apá bẹ̀rẹ̀ sí ro Mose, wọ́n gbé òkúta kan fún un láti fi jókòó, ó sì jókòó lórí rẹ̀. Aaroni ati Huri bá a gbé apá rẹ̀ sókè, ẹnìkan gbé apá ọ̀tún, ẹnìkejì sì gbé apá òsì. Apá rẹ̀ wà lókè títí tí oòrùn fi ń lọ wọ̀.

13. Joṣua bá fi idà pa Amaleki ati àwọn eniyan rẹ̀ ní ìpakúpa.

14. OLUWA bá sọ fún Mose pé, “Kọ ìṣẹ̀lẹ̀ yìí sinu ìwé kan fún ìrántí, sì kà á sí etígbọ̀ọ́ Joṣua, pé n óo pa Amaleki rẹ́ patapata, a kò sì ní ranti rẹ̀ mọ́ láyé.”

15. Mose bá tẹ́ pẹpẹ kan, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní “OLUWA ni àsíá mi.”

16. Ó ní, “Gbé àsíá OLUWA sókè! OLUWA yóo máa bá ìrandíran àwọn ará Amaleki jà títí lae.”

Ka pipe ipin Ẹkisodu 17