N óo dúró níwájú rẹ lórí àpáta ní òkè Horebu. Nígbà tí o bá fi ọ̀pá lu àpáta náà, omi yóo ti inú rẹ̀ jáde, àwọn eniyan náà yóo sì mu ún.” Mose bá ṣe bẹ́ẹ̀ níwájú gbogbo àwọn àgbààgbà Israẹli.