Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkisodu 17:1-7 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Gbogbo ìjọ eniyan Israẹli gbéra láti aṣálẹ̀ Sini, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí lọ láti ibùsọ̀ kan dé ekeji, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí OLUWA pa fún wọn. Wọ́n pàgọ́ sí Refidimu, ṣugbọn kò sí omi fún wọn láti mu.

2. Wọ́n bá ka ẹ̀sùn sí Mose lẹ́sẹ̀, wọ́n ní, “Fún wa ní omi tí a óo mu.”Mose dá wọn lóhùn pé, “Kí ló dé tí ẹ fi ka ẹ̀sùn sí mi lẹ́sẹ̀? Kí ló dé tí ẹ sì fi ń dán OLUWA wò?”

3. Ṣugbọn òùngbẹ ń gbẹ àwọn eniyan náà, wọ́n fẹ́ mu omi, wọ́n bá ń kùn sí Mose, wọ́n wí pé, “Kí ló dé tí o fi kó wa jáde láti ilẹ̀ Ijipti, láti fi òùngbẹ pa àwa ati àwọn ọmọ wa, ati àwọn ẹran ọ̀sìn wa?”

4. Mose bá tún kígbe pe OLUWA, ó ní, “Kí ni n óo ṣe sí àwọn eniyan wọnyi, wọ́n ti múra láti sọ mí lókùúta.”

5. OLUWA bá sọ fún Mose pé, “Mú ninu àwọn àgbààgbà ilẹ̀ Israẹli lọ́wọ́, kí ẹ jọ la ààrin àwọn eniyan náà kọjá, kí o sì mú ọ̀pá tí o fi lu odò Naili lọ́wọ́, bí o bá ti ń lọ.

6. N óo dúró níwájú rẹ lórí àpáta ní òkè Horebu. Nígbà tí o bá fi ọ̀pá lu àpáta náà, omi yóo ti inú rẹ̀ jáde, àwọn eniyan náà yóo sì mu ún.” Mose bá ṣe bẹ́ẹ̀ níwájú gbogbo àwọn àgbààgbà Israẹli.

7. Ó sì pe orúkọ ibẹ̀ ní Masa ati Meriba, nítorí ìwà ìka-ẹ̀sùn-síni-lẹ́sẹ̀ tí àwọn ọmọ Israẹli hù, ati nítorí dídán tí wọn dán OLUWA wò, wọ́n ní, “Ṣé OLUWA tún wà láàrin wa ni tabi kò sí mọ́?”

Ka pipe ipin Ẹkisodu 17