Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkisodu 13:9-22 BIBELI MIMỌ (BM)

9. Kí ó jẹ́ àmì ní ọwọ́ rẹ, ati ohun ìrántí láàrin ojú rẹ, kí òfin OLUWA lè wà ní ẹnu rẹ, nítorí pé pẹlu ipá ni OLUWA fi mú ọ jáde láti ilẹ̀ Ijipti wá.

10. Nítorí náà, ẹ máa ṣe ìrántí ìlànà yìí ní àkókò rẹ̀ ní ọdọọdún.

11. “Nígbà tí OLUWA bá mu yín dé ilẹ̀ àwọn ará Kenaani, gẹ́gẹ́ bí ó ti búra fún ẹ̀yin ati àwọn baba yín, tí ó bá sì fún yín ní ilẹ̀ náà,

12. gbogbo ohun tí ó bá ti jẹ́ àkọ́bí ni ẹ gbọdọ̀ yà sọ́tọ̀ fún OLUWA. Gbogbo àkọ́bí ẹran ọ̀sìn yín tí ó bá jẹ́ akọ, ti OLUWA ni.

13. Ẹ gbọdọ̀ fi ọ̀dọ́ aguntan ra gbogbo àkọ́bí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ yín pada, bí ẹ kò bá sì fẹ́ rà wọ́n pada, dandan ni pé kí ẹ lọ́ wọn lọ́rùn pa. Ẹ gbọdọ̀ ra gbogbo àkọ́bí yín tí wọ́n jẹ́ ọkunrin pada.

14. Ní ọjọ́ iwájú bí àwọn ọmọkunrin yín bá bèèrè ìtumọ̀ ohun tí ẹ̀ ń ṣe lọ́wọ́ yín, ohun tí ẹ óo wí fún wọn ni pé, ‘Pẹlu ipá ni OLUWA fi mú wa jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti, níbi tí a ti wà ní ìgbèkùn rí.

15. Nítorí pé nígbà tí Farao ṣe orí kunkun, tí ó sì kọ̀, tí kò jẹ́ kí á lọ, OLUWA pa gbogbo àwọn àkọ́bí ilẹ̀ Ijipti, ti eniyan ati ti ẹranko. Ìdí nìyí tí mo fi ń fi àkọ́bí ẹran ọ̀sìn mi, tí ó bá jẹ́ akọ rúbọ sí OLUWA, tí mo sì fi ń ra àwọn àkọ́bí mi ọkunrin pada.’

16. Ẹ fi ṣe àmì sí ọwọ́ yín, ati ìgbàjú sí iwájú yín, nítorí pé pẹlu ipá ni OLUWA fi mú wa jáde ní ilẹ̀ Ijipti.”

17. Nígbà tí Farao gbà pé kí àwọn ọmọ Israẹli máa lọ, Ọlọrun kò mú wọn gba ọ̀nà ilẹ̀ àwọn ará Filistia, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀nà ibẹ̀ yá, nítorí pé Ọlọrun rò ó ninu ara rẹ̀ pé, “Kí àwọn eniyan yìí má lọ yí ọkàn pada, bí àwọn kan bá gbógun tì wọ́n lójú ọ̀nà, kí wọ́n sì sá pada sí ilẹ̀ Ijipti.”

18. Ṣugbọn Ọlọrun mú kí wọ́n gba ọ̀nà aṣálẹ̀, ní agbègbè Òkun Pupa, àwọn eniyan Israẹli sì jáde láti ilẹ̀ Ijipti pẹlu ìmúrasílẹ̀ ogun.

19. Mose kó egungun Josẹfu lọ́wọ́ nígbà tí wọ́n ń lọ, nítorí pé Josẹfu ti mú kí àwọn ọmọ Israẹli jẹ́jẹ̀ẹ́, ó ní, “Ọlọrun yóo gbà yín là, nígbà tí ó bá yá tí ẹ̀ bá ń lọ, ẹ kó egungun mi lọ́wọ́ lọ.”

20. Wọ́n gbéra láti Sukotu, wọ́n pàgọ́ sí Etamu létí aṣálẹ̀.

21. OLUWA sì ń lọ níwájú wọn ní ọ̀sán ninu ọ̀wọ̀n ìkùukùu láti máa fi ọ̀nà hàn wọ́n, ati ní òru, ninu ọ̀wọ̀n iná láti máa fún wọn ní ìmọ́lẹ̀ kí wọ́n lè máa rìn ní ọ̀sán ati ní òru.

22. Ọ̀wọ̀n ìkùukùu kò fi ìgbà kan kúrò níwájú àwọn eniyan náà ní ọ̀sán, bẹ́ẹ̀ náà sì ni ọ̀wọ̀n iná ní òru.

Ka pipe ipin Ẹkisodu 13