Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkisodu 10:22-29 BIBELI MIMỌ (BM)

22. Mose bá gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè sí ojú ọ̀run, òkùnkùn biribiri sì ṣú bo gbogbo ilẹ̀ Ijipti fún odidi ọjọ́ mẹta.

23. Wọn kò lè rí ara wọn, bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò sì dìde kúrò níbi tí ó wà fún ọjọ́ mẹta. Ṣugbọn ìmọ́lẹ̀ wà ní gbogbo ibi tí àwọn ọmọ Israẹli ń gbé.

24. Farao bá tún ranṣẹ lọ pe Mose, ó ní, “Ẹ lọ sin Ọlọrun yín, ẹ máa kó àwọn ọmọ yín lọ pẹlu, ṣugbọn ẹ fi agbo aguntan yín ati agbo ẹran yín sílẹ̀.”

25. Mose dáhùn pé, “O níláti jẹ́ kí á kó ẹran tí a óo fi rúbọ lọ́wọ́, ati èyí tí a óo fi rúbọ sísun sí OLUWA Ọlọrun wa.

26. A níláti kó àwọn ẹran ọ̀sìn wa lọ, a kò ní fi ohunkohun sílẹ̀ lẹ́yìn, nítorí pé ninu wọn ni a óo ti mú láti fi rúbọ sí OLUWA Ọlọrun wa; a kò sì tíì mọ ohun tí a óo fi rúbọ, àfi ìgbà tí a bá débẹ̀.”

27. Ṣugbọn OLUWA Ọlọrun mú kí ọkàn Farao le, kò sì jẹ́ kí wọ́n lọ.

28. Farao bá lé Mose, ó ní, “Kúrò lọ́dọ̀ mi; kí o sì ṣọ́ra rẹ gidigidi, n kò gbọdọ̀ tún rí ọ níwájú mi mọ́; ní ọjọ́ tí mo bá tún fi ojú kàn ọ́, ọjọ́ náà ni o óo kú!”

29. Mose bá dáhùn, ó ní, “Bí o ti wí gan-an ni yóo rí. N kò ní dé iwájú rẹ mọ́.”

Ka pipe ipin Ẹkisodu 10