Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Diutaronomi 9:16-24 BIBELI MIMỌ (BM)

16. Ojú tí n óo gbé sókè, mo rí i pé ẹ ti ṣẹ̀ sí OLUWA Ọlọrun yín, ẹ ti yá ère wúrà tí ẹ fi iná yọ́, ẹ ti yára yipada kúrò ní ọ̀nà tí OLUWA Ọlọrun yín pa láṣẹ fun yín.

17. Mo bá mú àwọn tabili mejeeji, mo là wọ́n mọ́lẹ̀, mo sì fọ́ wọn lójú yín.

18. Mo bá dọ̀bálẹ̀ gbalaja níwájú OLUWA bíi ti àkọ́kọ́, fún ogoji ọjọ́; n kò jẹ, bẹ́ẹ̀ ni n kò sì mu, nítorí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí ẹ ti dá, tí ẹ ṣe ohun tí ó burú níwájú OLUWA, tí ẹ sì mú un bínú.

19. Nítorí inú tí OLUWA ń bí si yín ati inú rẹ̀ tí kò dùn sí yín bà mí lẹ́rù, nítorí ó ti ṣetán láti pa yín run. Ṣugbọn OLUWA tún gbọ́ ẹ̀bẹ̀ mi nígbà náà.

20. Inú bí OLUWA sí Aaroni tóbẹ́ẹ̀ tí OLUWA fi ṣetán láti pa á run, ṣugbọn mo gbadura fún Aaroni nígbà náà.

21. Mo bá gbé ère ọmọ mààlúù tí ẹ yá, tí ó jẹ́ ohun ẹ̀ṣẹ̀, mo dáná sun ún, mo lọ̀ ọ́ lúbúlúbú, mo sì dà á sinu odò tí ń ṣàn wá láti orí òkè.

22. “Bẹ́ẹ̀ ni ẹ mú OLUWA bínú ní Tabera ati ní Masa, ati ni Kibiroti Hataafa.

23. Bákan náà ni ẹ ṣe ní Kadeṣi Banea, nígbà tí OLUWA ran yín lọ, tí ó ní kí ẹ lọ gba ilẹ̀ tí òun ti fi fun yín. Ẹ ṣe orí kunkun sí àṣẹ OLUWA Ọlọrun yín, ẹ kò gbà á gbọ́, ẹ kò sì tẹ̀lé ọ̀rọ̀ rẹ̀.

24. Láti ìgbà tí mo ti mọ̀ yín, kò sí ìgbà kan tí ẹ kò ṣe orí kunkun sí OLUWA.

Ka pipe ipin Diutaronomi 9