Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Diutaronomi 8:9-18 BIBELI MIMỌ (BM)

9. Ilẹ̀ tí ẹ óo ti máa jẹun, tí kò ní sí ọ̀wọ́n oúnjẹ, níbi tí ẹ kò ní ṣe aláìní ohunkohun. Ilẹ̀ tí òkúta rẹ̀ jẹ́ irin, tí ẹ óo sì máa wa idẹ lára àwọn òkè rẹ̀.

10. Nígbà tí ẹ bá jẹun, tí ẹ yó, ẹ óo dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA Ọlọrun yín fún ilẹ̀ dáradára tí ó fun yín.

11. “Ẹ ṣọ́ra, kí ẹ má gbàgbé OLUWA Ọlọrun yín, nípa àìpa àwọn òfin ati ìlànà rẹ̀ mọ́, ati ìdájọ́ rẹ̀ tí mo fun yín lónìí,

12. kí ó má jẹ́ pé, nígbà tí ẹ bá jẹun, tí ẹ yó tán, tí ẹ ti kọ́ àwọn ilé dáradára, tí ẹ sì ń gbé inú wọn,

13. nígbà tí agbo mààlúù yín ati agbo aguntan yín bá pọ̀ sí i, tí wúrà ati fadaka yín náà sì pọ̀ sí i, tí ohun gbogbo tí ẹ ní bá pọ̀ sí i,

14. kí ìgbéraga má gba ọkàn yín, kí ẹ sì gbàgbé OLUWA Ọlọrun yín, tí ó mu yín jáde láti ilẹ̀ Ijipti, níbi tí ẹ ti ń ṣe ẹrú.

15. Ẹni tí ó mú yín la aṣálẹ̀ ńlá tí ó bani lẹ́rù já, aṣálẹ̀ tí ó kún fún ejò olóró ati àkeekèé, tí ilẹ̀ rẹ̀ gbẹ, tí kò sì sí omi, OLUWA tí ó mú omi jáde fun yín láti inú akọ òkúta,

16. ẹni tí ó fi mana tí àwọn baba yín kò jẹ rí bọ́ yín ninu aṣálẹ̀, kí ó lè tẹ orí yín ba, kí ó sì dán yín wò láti ṣe yín ní rere níkẹyìn.

17. Ẹ ṣọ́ra, kí ẹ má baà sọ ninu ọkàn yín pé agbára yín, ati ipá yín ni ó mú ọrọ̀ yìí wá fun yín.

18. Ẹ ranti OLUWA Ọlọrun yín nítorí òun ni ó fun yín ní agbára láti di ọlọ́rọ̀, kí ó lè fìdí majẹmu tí ó fi ìbúra bá àwọn baba yín dá múlẹ̀, bí ó ti rí lónìí.

Ka pipe ipin Diutaronomi 8