Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Diutaronomi 8:14-20 BIBELI MIMỌ (BM)

14. kí ìgbéraga má gba ọkàn yín, kí ẹ sì gbàgbé OLUWA Ọlọrun yín, tí ó mu yín jáde láti ilẹ̀ Ijipti, níbi tí ẹ ti ń ṣe ẹrú.

15. Ẹni tí ó mú yín la aṣálẹ̀ ńlá tí ó bani lẹ́rù já, aṣálẹ̀ tí ó kún fún ejò olóró ati àkeekèé, tí ilẹ̀ rẹ̀ gbẹ, tí kò sì sí omi, OLUWA tí ó mú omi jáde fun yín láti inú akọ òkúta,

16. ẹni tí ó fi mana tí àwọn baba yín kò jẹ rí bọ́ yín ninu aṣálẹ̀, kí ó lè tẹ orí yín ba, kí ó sì dán yín wò láti ṣe yín ní rere níkẹyìn.

17. Ẹ ṣọ́ra, kí ẹ má baà sọ ninu ọkàn yín pé agbára yín, ati ipá yín ni ó mú ọrọ̀ yìí wá fun yín.

18. Ẹ ranti OLUWA Ọlọrun yín nítorí òun ni ó fun yín ní agbára láti di ọlọ́rọ̀, kí ó lè fìdí majẹmu tí ó fi ìbúra bá àwọn baba yín dá múlẹ̀, bí ó ti rí lónìí.

19. Ṣugbọn, mò ń kìlọ̀ fun yín dáradára lónìí pé, bí ẹ bá gbàgbé OLUWA Ọlọrun yín, tí ẹ̀ ń sá káàkiri tọ àwọn oriṣa lẹ́yìn, tí ẹ sì ń bọ wọ́n, píparun ni ẹ óo parun.

20. Gẹ́gẹ́ bí àwọn orílẹ̀-èdè tí OLUWA parun fun yín, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin náà yóo parun, nítorí pé ẹ kọ̀, ẹ kò gbọ́ ti OLUWA Ọlọrun yín.

Ka pipe ipin Diutaronomi 8