Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Diutaronomi 4:40-48 BIBELI MIMỌ (BM)

40. Nítorí náà, ẹ máa pa àwọn ìlànà ati òfin rẹ̀ tí mo fun yín lónìí mọ́, kí ó lè dára fun yín, ati fún àwọn ọmọ yín; kí ẹ lè pẹ́ lórí ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín fun yín, títí lae.”

41. Mose ya ìlú mẹta sọ́tọ̀ ní ìhà ìlà oòrùn odò Jọdani, gẹ́gẹ́ bí ìlú ààbò,

42. kí ẹnikẹ́ni tí ó bá paniyan lè máa sálọ sibẹ; kí ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣèèṣì pa aládùúgbò rẹ̀, láìjẹ́ pé wọ́n ní ìkùnsínú sí ara wọn tẹ́lẹ̀, lè sálọ sí ọ̀kan ninu àwọn ìlú wọnyi, kí ó lè gba ẹ̀mí ara rẹ̀ là.

43. Ó ya Beseri sọ́tọ̀ fún ẹ̀yà Reubẹni ninu aṣálẹ̀ láàrin ilẹ̀ tí ó tẹ́jú. Ó ya Ramoti sọ́tọ̀ ní Gileadi, fún ẹ̀yà Gadi, ó sì ya Golani sọ́tọ̀ ní Baṣani, fún ẹ̀yà Manase.

44. Mose fún àwọn ọmọ Israẹli ní àwọn òfin;

45. ó sì fi àwọn ìlànà ati àṣẹ lélẹ̀ fún wọn nígbà tí wọ́n jáde kúrò ní Ijipti,

46. nígbà tí wọ́n dé òdìkejì odò Jọdani, ní àfonífojì tí ó dojú kọ Betipeori, ní ilẹ̀ Sihoni, ọba àwọn ará Amori tí ń gbé Heṣiboni. Mose ati àwọn ọmọ Israẹli ṣẹgun Sihoni nígbà tí wọ́n jáde kúrò ní Ijipti.

47. Wọ́n gba ilẹ̀ rẹ̀ ati ilẹ̀ Ogu, ọba Baṣani, Sihoni ati Ogu ni ọba àwọn ará Amori tí wọn ń gbé òdìkejì odò Jọdani ní apá ìlà oòrùn

48. láti Aroeri tí ó wà ní etí àfonífojì Anoni títí dé òkè Sirioni (tí à ń pè ní òkè Herimoni),

Ka pipe ipin Diutaronomi 4