Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Diutaronomi 34:5-10 BIBELI MIMỌ (BM)

5. Mose iranṣẹ OLUWA kú ní ilẹ̀ Moabu gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ OLUWA.

6. OLUWA sin ín sí àfonífojì ilẹ̀ Moabu tí ó dojú kọ Betipeori, ṣugbọn ẹnikẹ́ni kò mọ ibojì rẹ̀ títí di òní olónìí.

7. Mose jẹ́ ẹni ọgọfa (120) ọdún nígbà tí ó kú, ojú rẹ̀ kò ṣe bàìbàì, bẹ́ẹ̀ ni agbára rẹ̀ kò dínkù.

8. Àwọn ọmọ Israẹli ṣọ̀fọ̀ Mose fún ọgbọ̀n ọjọ́ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu, wọ́n sì parí ṣíṣe òkú rẹ̀.

9. Joṣua ọmọ Nuni kún fún ọgbọ́n nítorí pé Mose ti gbé ọwọ́ rẹ̀ lé e, nítorí náà àwọn ọmọ Israẹli ń gbọ́ tirẹ̀, wọ́n sì ń ṣe gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí OLUWA pa fún Mose.

10. Láti ìgbà náà, kò tíì sí wolii mìíràn ní ilẹ̀ Israẹli tí ó dàbí Mose, ẹni tí Ọlọrun bá sọ̀rọ̀ lojukooju.

Ka pipe ipin Diutaronomi 34