Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Diutaronomi 32:22-33 BIBELI MIMỌ (BM)

22. Nítorí iná ibinu mi ń jó,yóo sì jó títí dé isà òkú.Yóo jó ayé ati ohun gbogbo tí ń bẹ ninu rẹ̀ ní àjórun,tó fi mọ́ ìpìlẹ̀ àwọn òkè ńlá.

23. “ ‘N óo da oríṣìíríṣìí ibi sórí wọn,n óo sì rọ òjò ọfà mi sára wọn.

24. N óo fi ebi pa wọ́n ní àpakú,iná yóo jó wọn ní àjórun,n óo sì fi àjàkálẹ̀ àrùn pa wọ́n run.N óo jẹ́ kí àwọn ẹranko burúkú pa wọ́n jẹ,n óo sì jẹ́ kí àwọn ejò olóró bù wọ́n ṣán.

25. Bí idà tí ń pa àwọn kan lójú pópó,bẹ́ẹ̀ ni ikú yóo di ẹ̀rù jẹ̀jẹ̀ láàrin ọ̀dẹ̀dẹ̀.Bó ti ń pa àwọn ọdọmọkunrin, bẹ́ẹ̀ ni yóo máa pa àwọn ọdọmọbinrin,ati àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ ati àwọn arúgbó kùjọ́kùjọ́,gbogbo wọn ni ikú gbígbóná yóo máa mú lọ.

26. Ǹ bá wí pé kí n fọ́n wọn káàkiri,kí ẹnikẹ́ni má tilẹ̀ ranti wọn mọ́,

27. ti àwọn ọ̀tá wọn ni mo rò,nítorí pé, ọ̀tọ̀ ni ohun tí wọn yóo máa wí kiri.Wọn yóo máa wí pé,“Àwa ni a ṣẹgun wọn,kìí ṣe OLUWA ló ṣe é rárá.” ’

28. “Nítorí pé aláìlérò orílẹ̀-èdè ni Israẹli,òye kò sì yé wọn rárá.

29. Bí ó bá ṣe pé wọ́n gbọ́n ni,tí òye sì yé wọn;wọn ì bá ti mọ̀ bí ìgbẹ̀yìn wọn yóo ti rí.

30. Ẹyọ ẹnìkan ṣoṣo ṣe lè lé ẹgbẹrun eniyan?Àní, eniyan meji péré ṣe lè lé ẹgbaarun eniyan sá?Bí kò bá jẹ́ pé Ọlọrun aláàbò wọn ti kọ̀ wọ́n sílẹ̀,tí OLUWA sì ti fi wọ́n lé àwọn ọ̀tá wọn lọ́wọ́.

31. Nítorí pé, àwọn ọ̀tá wọn pàápàá mọ̀ pé,Ọlọrun, aláàbò Israẹli, kì í ṣe ẹgbẹ́ àwọn oriṣa wọn.

32. Àwọn ọ̀tá wọn ti bàjẹ́ bíi Sodomu ati Gomora,wọ́n dàbí àjàrà tí ń so èso tí ó korò tí ó sì lóró.

33. Oró ejò ni ọtí wọn,àní oró paramọ́lẹ̀ tíí ṣe ikú pani.

Ka pipe ipin Diutaronomi 32