Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Diutaronomi 32:12-21 BIBELI MIMỌ (BM)

12. OLUWA nìkan ṣoṣo ni ó ṣáájú àwọn eniyan rẹ̀,láìsí ìrànlọ́wọ́ oriṣa kankan.

13. “Ó fi wọ́n jọba lórí àwọn òkè ayé,ó sì fún wọn ní èso ilẹ̀ jẹ.Ó pèsè oyin fún wọn láti inú àpáta,ó sì mú kí igi olifi hù fún wọn lórí ilẹ̀ olókùúta.

14. Wọn rí ọpọlọpọ wàrà lára mààlúù wọn,ati ọ̀pọ̀ omi wàrà lára ewúrẹ́ wọn,ó fún wọn ní ọ̀rá ọ̀dọ́ aguntan ati ti àgbò,ó fún wọn ní mààlúù Baṣani, ati ewúrẹ́,ati ọkà tí ó dára jùlọ,ati ọpọlọpọ ọtí waini.

15. “Ṣugbọn ẹ̀yin ọmọ Jeṣuruni, ẹ yó tán,ẹ wá tàpá sí àṣẹ;ẹ rí jẹ, ẹ rí mu, ẹ sì lókun lára;ẹ wá gbàgbé Ọlọrun tí ó da yín,ẹ sì ń pẹ̀gàn àpáta ìgbàlà yín!

16. Wọ́n fi ìbọ̀rìṣà wọn sọ OLUWA di òjòwú;wọ́n fi ìwà burúkú wọn mú kí ibinu OLUWA wọn ru sókè.

17. Wọ́n tún bẹ̀rẹ̀ sí rúbọ sí àwọn ẹ̀mí burúkú,Àwọn oriṣa tí wọn kò mọ̀ rí,tí àwọn baba wọn kò sì bọ rí.

18. Ẹ gbàgbé àpáta ìgbàlà yín,ẹ gbàgbé Ọlọrun tí ó da yín.

19. “Nígbà tí OLUWA rí ohun tí àwọn ọmọ rẹ̀ ń ṣe,ó kọ̀ wọ́n sílẹ̀,nítorí pé, wọ́n mú un bínú.

20. Ó ní, ‘N óo mójú kúrò lára wọn,n óo sì máa wò bí ìgbẹ̀yìn wọn yóo ti rí.Nítorí olóríkunkun ni wọ́n,àwọn alaiṣootọ ọmọ!

21. Nítorí oriṣa lásánlàsàn,wọn sọ èmi Ọlọrun di òjòwú;wọn sì ti fi àwọn ère wọn mú mi bínú.Nítorí náà, èmi náà óo lo àwọn eniyan lásánlàsànláti mu àwọn náà jowú,n óo sì lo aṣiwèrè orílẹ̀-èdè lásánlàsàn kanláti mú wọn bínú.

Ka pipe ipin Diutaronomi 32