Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Diutaronomi 25:8-19 BIBELI MIMỌ (BM)

8. Àwọn àgbààgbà ìlú yóo pe ọkunrin náà, wọn óo bá a sọ̀rọ̀, bí ó bá kọ̀ jálẹ̀, tí ó wí pé, ‘Èmi kò fẹ́ fẹ́ ẹ,’

9. Lẹ́yìn náà, obinrin náà yóo tọ̀ ọ́ lọ lójú gbogbo àwọn àgbààgbà, yóo bọ́ bàtà ẹsẹ̀ rẹ̀, yóo tutọ́ sí i lójú, yóo sì wí pé, ‘Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe sí ẹni tí ó bá kọ̀ láti kọ́ ilé arakunrin rẹ̀.’

10. Wọn yóo sì máa pe ìdílé rẹ̀ ní ìdílé ẹni tí wọ́n bọ́ bàtà lẹ́sẹ̀ rẹ̀.

11. “Bí ọkunrin meji bá ń jà, tí iyawo ọ̀kan ninu wọn bá sáré wá láti gbèjà ọkọ rẹ̀ tí wọn ń lù, tí ó bá fa nǹkan ọkunrin ẹni tí ń lu ọkọ rẹ̀ yìí,

12. gígé ni kí ẹ gé ọwọ́ rẹ̀, ẹ kò gbọdọ̀ ṣàánú rẹ̀ rárá.

13. “O kò gbọdọ̀ ní oríṣìí ìwọ̀n meji ninu àpò rẹ, kí ọ̀kan kéré, kí ekeji sì tóbi.

14. O kò gbọdọ̀ ní oríṣìí òṣùnwọ̀n meji ninu ilé rẹ, kí ọ̀kan kéré, kí ekeji sì tóbi.

15. Ṣugbọn ìwọ̀n ati òṣùnwọ̀n rẹ gbọdọ̀ péye, kí ọjọ́ rẹ lè pẹ́ lórí ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun rẹ fún ọ.

16. Nítorí pé ẹnikẹ́ni tí ó bá ń ṣe aiṣootọ, ìríra ni lójú OLUWA Ọlọrun yín.

17. “Ẹ ranti ohun tí àwọn ará Amaleki ṣe sí yín nígbà tí ẹ̀ ń bọ̀ láti Ijipti.

18. Wọn kò bẹ̀rù Ọlọrun, ṣugbọn wọ́n gbógun tì yín lójú ọ̀nà nígbà tí ó ti rẹ̀ yín, wọ́n sì pa gbogbo àwọn tí wọn ń bọ̀ lẹ́yìn.

19. Nítorí náà nígbà tí OLUWA Ọlọrun yín bá fun yín ní ìṣẹ́gun lórí gbogbo àwọn ọ̀tá yín tí wọ́n wà ní àyíká yín, ní ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín fun yín, pípa ni kí ẹ pa àwọn ará Amaleki run lórí ilẹ̀ ayé. Ẹ kò gbọdọ̀ gbàgbé.

Ka pipe ipin Diutaronomi 25