Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Diutaronomi 25:4-14 BIBELI MIMỌ (BM)

4. “Ẹ kò gbọdọ̀ dí mààlúù lẹ́nu nígbà tí ẹ bá ń lò ó láti fi pa ọkà.

5. “Bí àwọn arakunrin meji bá jùmọ̀ ń gbé pọ̀, tí ọ̀kan ninu wọn sì kú láìní ọmọkunrin, aya ẹni tí ó kú kò gbọdọ̀ lọ fẹ́ ará ìta tabi àlejò. Arakunrin ọkọ rẹ̀ ni ó gbọdọ̀ ṣú u lópó, kí ó sì máa ṣe gbogbo ẹ̀tọ́ tí ó bá yẹ fún obinrin náà.

6. Wọn yóo ka ọmọkunrin kinni tí opó yìí bá bí sí ọmọ ọkọ rẹ̀ tí ó kú, kí orúkọ ọkọ rẹ̀ náà má baà parẹ́ ní Israẹli.

7. Bí ọkunrin yìí kò bá wá fẹ́ ṣú aya arakunrin rẹ̀ tí ó kú lópó, obinrin náà yóo tọ àwọn àgbààgbà lọ ní ẹnubodè, yóo sì wí pé, ‘Arakunrin ọkọ mi kọ̀ láti gbé orúkọ arakunrin rẹ̀ ró ní Israẹli, ó kọ̀ láti ṣe ojúṣe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí arakunrin ọkọ mi.’

8. Àwọn àgbààgbà ìlú yóo pe ọkunrin náà, wọn óo bá a sọ̀rọ̀, bí ó bá kọ̀ jálẹ̀, tí ó wí pé, ‘Èmi kò fẹ́ fẹ́ ẹ,’

9. Lẹ́yìn náà, obinrin náà yóo tọ̀ ọ́ lọ lójú gbogbo àwọn àgbààgbà, yóo bọ́ bàtà ẹsẹ̀ rẹ̀, yóo tutọ́ sí i lójú, yóo sì wí pé, ‘Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe sí ẹni tí ó bá kọ̀ láti kọ́ ilé arakunrin rẹ̀.’

10. Wọn yóo sì máa pe ìdílé rẹ̀ ní ìdílé ẹni tí wọ́n bọ́ bàtà lẹ́sẹ̀ rẹ̀.

11. “Bí ọkunrin meji bá ń jà, tí iyawo ọ̀kan ninu wọn bá sáré wá láti gbèjà ọkọ rẹ̀ tí wọn ń lù, tí ó bá fa nǹkan ọkunrin ẹni tí ń lu ọkọ rẹ̀ yìí,

12. gígé ni kí ẹ gé ọwọ́ rẹ̀, ẹ kò gbọdọ̀ ṣàánú rẹ̀ rárá.

13. “O kò gbọdọ̀ ní oríṣìí ìwọ̀n meji ninu àpò rẹ, kí ọ̀kan kéré, kí ekeji sì tóbi.

14. O kò gbọdọ̀ ní oríṣìí òṣùnwọ̀n meji ninu ilé rẹ, kí ọ̀kan kéré, kí ekeji sì tóbi.

Ka pipe ipin Diutaronomi 25