Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Diutaronomi 25:1-9 BIBELI MIMỌ (BM)

1. “Bí èdè-àìyedè kan bá bẹ́ sílẹ̀ láàrin àwọn ọmọ meji, tí wọ́n bá lọ sí ilé ẹjọ́, tí àwọn adájọ́ sì dá ẹjọ́ náà fún wọn, tí wọ́n dá ẹni tí ó jàre láre, tí wọ́n sì dá ẹni tí ó jẹ̀bi lẹ́bi,

2. bí ó bá jẹ́ pé nínà ni ó yẹ kí wọ́n na ẹni tí ó jẹ̀bi, ẹni náà yóo dọ̀bálẹ̀ níwájú adájọ́, wọn yóo sì nà án ní iye ẹgba tí ó bá tọ́ sí i gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.

3. Ṣugbọn wọn kò gbọdọ̀ nà án ju ogoji ẹgba lọ, ohun ìtìjú ni yóo jẹ́ fún un ní gbangba, bí wọ́n bá nà án jù bẹ́ẹ̀ lọ.

4. “Ẹ kò gbọdọ̀ dí mààlúù lẹ́nu nígbà tí ẹ bá ń lò ó láti fi pa ọkà.

5. “Bí àwọn arakunrin meji bá jùmọ̀ ń gbé pọ̀, tí ọ̀kan ninu wọn sì kú láìní ọmọkunrin, aya ẹni tí ó kú kò gbọdọ̀ lọ fẹ́ ará ìta tabi àlejò. Arakunrin ọkọ rẹ̀ ni ó gbọdọ̀ ṣú u lópó, kí ó sì máa ṣe gbogbo ẹ̀tọ́ tí ó bá yẹ fún obinrin náà.

6. Wọn yóo ka ọmọkunrin kinni tí opó yìí bá bí sí ọmọ ọkọ rẹ̀ tí ó kú, kí orúkọ ọkọ rẹ̀ náà má baà parẹ́ ní Israẹli.

7. Bí ọkunrin yìí kò bá wá fẹ́ ṣú aya arakunrin rẹ̀ tí ó kú lópó, obinrin náà yóo tọ àwọn àgbààgbà lọ ní ẹnubodè, yóo sì wí pé, ‘Arakunrin ọkọ mi kọ̀ láti gbé orúkọ arakunrin rẹ̀ ró ní Israẹli, ó kọ̀ láti ṣe ojúṣe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí arakunrin ọkọ mi.’

8. Àwọn àgbààgbà ìlú yóo pe ọkunrin náà, wọn óo bá a sọ̀rọ̀, bí ó bá kọ̀ jálẹ̀, tí ó wí pé, ‘Èmi kò fẹ́ fẹ́ ẹ,’

9. Lẹ́yìn náà, obinrin náà yóo tọ̀ ọ́ lọ lójú gbogbo àwọn àgbààgbà, yóo bọ́ bàtà ẹsẹ̀ rẹ̀, yóo tutọ́ sí i lójú, yóo sì wí pé, ‘Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe sí ẹni tí ó bá kọ̀ láti kọ́ ilé arakunrin rẹ̀.’

Ka pipe ipin Diutaronomi 25