Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Diutaronomi 22:25-30 BIBELI MIMỌ (BM)

25. “Ṣugbọn bí ó bá jẹ́ pé ninu igbó ni ọkunrin kan ti ki ọmọbinrin kan tí ó jẹ́ àfẹ́sọ́nà ẹnìkan mọ́lẹ̀, tí ó sì bá a lòpọ̀, ọkunrin nìkan ni kí wọ́n pa.

26. Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe ohunkohun sí ọmọbinrin náà, kò jẹ̀bi ikú rárá, nítorí ọ̀rọ̀ náà dàbí pé kí ọkunrin kan pàdé aládùúgbò rẹ̀ kan lójú ọ̀nà, kí ó sì lù ú pa.

27. Nítorí pé, inú igbó ni ó ti kì í mọ́lẹ̀. Bí ọmọbinrin àfẹ́sọ́nà yìí tilẹ̀ ké: ‘Gbà mí! Gbà mí!’ Kò sí ẹnikẹ́ni nítòsí tí ó lè gbà á sílẹ̀.

28. “Bí ọkunrin kan bá rí ọmọbinrin kan, tí kì í ṣe àfẹ́sọ́nà ẹnikẹ́ni, tí ó kì í mọ́lẹ̀, tí ó sì bá a lòpọ̀, bí ọwọ́ bá tẹ̀ wọ́n,

29. ọkunrin tí ó bá obinrin yìí lòpọ̀ níláti fún baba ọmọbinrin náà ní aadọta ìwọ̀n ṣekeli fadaka. Ọmọbinrin yìí yóo sì di iyawo rẹ̀, nítorí pé ó ti fi ipá bá a lòpọ̀, kò sì gbọdọ̀ kọ̀ ọ́ sílẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀.

30. “Ọkunrin kò gbọdọ̀ fi èyíkéyìí ninu àwọn aya baba rẹ̀ ṣe aya, tabi kí ó bá a lòpọ̀.

Ka pipe ipin Diutaronomi 22