Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Diutaronomi 20:9-20 BIBELI MIMỌ (BM)

9. Nígbà tí àwọn ọ̀gágun bá parí ọ̀rọ̀ tí wọn ń bá àwọn eniyan náà sọ, wọn óo yan àwọn kan tí wọn óo máa ṣe aṣaaju ìsọ̀rí-ìsọ̀rí àwọn jagunjagun.

10. “Bí ẹ bá ti súnmọ́ ìlú tí ẹ fẹ́ bá jagun, ẹ kọ́ rán iṣẹ́ alaafia sí wọn.

11. Bí wọ́n bá rán iṣẹ́ alaafia pada, tí wọ́n sì ṣí ìlẹ̀kùn wọn fun yín, kí ẹ kó gbogbo àwọn ará ìlú náà lẹ́rú kí wọ́n sì máa sìn yín.

12. Ṣugbọn bí wọ́n bá kọ̀, tí àwọn náà dìde ogun si yín, ẹ dó ti ìlú náà.

13. Nígbà tí OLUWA Ọlọrun yín bá fi ìlú náà le yín lọ́wọ́, kí ẹ fi idà pa gbogbo àwọn ọkunrin tí wọ́n wà níbẹ̀.

14. Ṣugbọn kí ẹ dá àwọn obinrin ati àwọn ọmọ wọn sí, ati àwọn ẹran ọ̀sìn wọn, ati gbogbo dúkìá yòókù tí ó wà ninu ìlú náà, kí ẹ kó gbogbo rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìkógun fún ara yín, kí ẹ máa lo gbogbo dúkìá àwọn ọ̀tá yín tí OLUWA Ọlọrun yín ti fun yín.

15. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ṣe sí àwọn ìlú tí ó jìnnà sí yín, tí kì í ṣe àwọn ìlú orílẹ̀-èdè tí ó wà níhìn-ín.

16. “Ṣugbọn gbogbo àwọn ìlú tí ó wà ninu àwọn orílẹ̀-èdè tí OLUWA Ọlọrun yín yóo fi fun yín, gẹ́gẹ́ bí ìní yín, ẹ kò gbọdọ̀ dá ohun alààyè kan sí ninu wọn.

17. Rírun ni kí ẹ run gbogbo wọn patapata, gbogbo àwọn ará Hiti, ati àwọn ará Amori, ati àwọn ará Kenaani, ati àwọn ará Perisi, ati àwọn ará Hifi, ati àwọn ará Jebusi; gẹ́gẹ́ bí OLUWA Ọlọrun yín ti pa á láṣẹ.

18. Kí wọ́n má baà kọ yín ní ìkọ́kúkọ̀ọ́, kí ẹ má baà máa ṣe oríṣìíríṣìí àwọn ohun ìríra tí wọn ń ṣe nígbà tí wọ́n bá ń bọ àwọn oriṣa wọn, kí ẹ má baà dẹ́ṣẹ̀ sí OLUWA Ọlọrun yín.

19. “Nígbà tí ẹ bá dó ti ìlú kan fún ìgbà pípẹ́, tí ẹ bá ń bá ìlú náà jagun tí ẹ fẹ́ gbà á, ẹ kò gbọdọ̀ bẹ́ àwọn igi eléso wọn lulẹ̀ ní ìbẹ́kúbẹ̀ẹ́. Jíjẹ ni kí ẹ máa jẹ èso igi wọn, ẹ kò gbọdọ̀ gé wọn lulẹ̀. Àbí eniyan ni igi inú igbó, tí ẹ óo fi máa gbé ogun tì í?

20. Àwọn igi tí ẹ bá mọ̀ pé èso wọn kìí ṣe jíjẹ nìkan ni kí ẹ máa gé, kí ẹ máa fi ṣe àtẹ̀gùn, tí ẹ fi lè wọ ìlú náà, títí tí ọwọ́ yín yóo fi tẹ̀ ẹ́.

Ka pipe ipin Diutaronomi 20