Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Diutaronomi 2:25-37 BIBELI MIMỌ (BM)

25. Láti òní lọ, n óo mú kí ẹ̀rù yín máa ba gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n wà láyé yìí, tí wọ́n bá gbúròó yín, wọn yóo máa gbọ̀n, ojora yóo sì mú wọn nítorí yín.

26. “Nítorí náà mo rán àwọn oníṣẹ́ láti aṣálẹ̀ Kedemotu, sí Sihoni, ọba Heṣiboni. Iṣẹ́ alaafia ni mo rán sí i, mo ní,

27. ‘Jẹ́ kí n kọjá láàrin ilẹ̀ rẹ. Ojú ọ̀nà tààrà ni n óo máa gbà lọ. N kò ní yà sí ọ̀tún tabi sí òsì.

28. Rírà ni n óo ra oúnjẹ tí n óo jẹ lọ́wọ́ rẹ, n óo sì ra omi tí n óo mu pẹlu. Ṣá ti gbà mí láàyè kí n kọjá,

29. bí àwọn ọmọ Esau, tí wọn ń gbé Seiri ati àwọn ará Moabu tí wọn ń gbé Ari, ti ṣe fún mi, títí tí n óo fi kọjá odò Jọdani, lọ sí ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun wa ti fi fún wa.’

30. “Ṣugbọn Sihoni, ọba Heṣiboni kọ̀ fún wa, kò jẹ́ kí á kọjá lọ́dọ̀ rẹ̀; nítorí OLUWA Ọlọrun yín mú kí ọkàn rẹ̀ le, ó sì mú kí ó ṣe oríkunkun, kí ó lè fi le yín lọ́wọ́, bí ó ti ṣe lónìí.

31. “OLUWA sọ fún mi pé, ‘Wò ó, mo ti bẹ̀rẹ̀ sí fi Sihoni ati ilẹ̀ rẹ̀ le yín lọ́wọ́, ẹ bẹ̀rẹ̀ sí gbà á, kí ẹ lè máa gbé ibẹ̀.’

32. Sihoni bá jáde sí wa, òun ati àwọn eniyan rẹ̀, láti bá wa jagun ní Jahasi.

33. OLUWA Ọlọrun wa fi lé wa lọ́wọ́, a ṣẹgun rẹ̀, ati òun ati àwọn ọmọ rẹ̀, ati gbogbo àwọn eniyan rẹ̀.

34. A gba àwọn ìlú ńláńlá rẹ̀ nígbà náà, a sì run wọ́n, ati ọkunrin, ati obinrin, ati àwọn ọmọ wọn. A kò dá ohunkohun sí,

35. àfi àwọn ohun ọ̀sìn tí a kó bí ìkógun, pẹlu àwọn ìkógun tí a kó ninu àwọn ìlú tí a gbà.

36. Láti Aroeri tí ó wà ní etí àfonífojì Anoni lọ, ati ìlú ńlá tí ó wà ní àfonífojì, títí dé Gileadi, kò sí ìlú tí ó ju agbára wa lọ. OLUWA Ọlọrun wa fi gbogbo wọn lé wa lọ́wọ́,

37. àfi ilẹ̀ àwọn ọmọ Amoni nìkan ni ẹ kò súnmọ́, àwọn ilẹ̀ tí ó wà ní etí odò Jaboku, ati àwọn ìlú ńláńlá tí ó wà ní agbègbè olókè, ati gbogbo ibi tí OLUWA Ọlọrun wa ti paláṣẹ pé a kò gbọdọ̀ dé.

Ka pipe ipin Diutaronomi 2